Okorie wọṣọ ọlọpaa, Usman wọ ti ṣọja, ni wọn ba fi n lu jibiti kiri Eko

Faith Adebọla, Eko

 

 

Ẹwọn ti n run nimu awọn ọkunrin meji kan tọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣẹṣẹ ba, Okorie Anya, ẹni ọdun marundinlaaadọta, ati Usman Ali, ẹni ọdun mọkanlelogun, aṣọ ọlọpaa ati ti ṣọja lawọn mejeeji fi n lu jibiti l’Ekoo, ti wọn fi mu wọn.

Okorie to n wọṣọ ọlọpaa, Ojule keje, Opopona Alabata, lagbegbe Ikọtun, nipinlẹ Eko, loun n gbe, ṣugbọn boya tori ki awọn ti wọn mọ ọn dele ma le tu aṣiri rẹ ni o, boya agbegbe Ketu si ni ọkanjuwa rẹ so si ni o, oun nikan lo le sọ, to fi jẹ pe Ketu lo maa n wa lojoojumọ, ibẹ lo ti n ṣe bii ọlọpaa tootọ, to si n fi yunifọọmu ọlọpaa to ko sọrun lu araalu ni jibiti.

Usman ni tiẹ, Ojule kọkanlelaaadọta, Opopona Ali Balogun, lagbegbe Ijọra Oloye, ni wọn loun n gbe, ṣugbọn awọn ọlọpaa teṣan Surulere ni wọn mu un pẹlu yunifọọmu ṣọja eke to wọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejọbi, sọ pe ipo inpẹkitọ ni Okorie n sọ fawọn eeyan pe oun wa ninu iṣẹ ọlọpaa, okun ati irawọ inpẹkitọ naa lo si wa lejika ẹ, ṣugbọn wọn ni feeki lawọn ami idanimọ wọnyẹn, okun naa kan jọ tileeṣẹ ọlọpaa ni, wọn ki i ṣe ojulowo rara.

Awọn nnkan mi-in ti wọn tun ka mọ afurasi ọdaran yii lọwọ nigba ti wọn lọọ yẹ ile ẹ wo ni fila ọlọpaa mòpóò (mopol) meji, okun ẹ̀yẹ ọlọpaa meji, ṣokoto ọlọpaa meji, ẹwu awọtẹlẹ ọlọpaa mopoo meji, ọbẹ, atawọn ẹsibiiti mi-in.

Ileeṣẹ ọlọpaa lawọn ti pari iwe ẹsun awọn afurasi mejeeji yii, ẹsun pipe ara wọn ni ohun ti wọn ko jẹ ati fifi dukia ijọba lu jibiti ni wọn fi kan wọn.

Wọn lawọn mejeeji maa too bẹrẹ si i ṣalaye ohun ti wọn jẹ yo ti wọn fi n fi aṣọ ọlọpaa ati ṣọja lu jibiti

Leave a Reply