Oku Blessing tawọn eeyan ba ni yara ẹ ko pe mọ, wọn ti ge ori, ọmu ati oju ara ẹ lọ

 Obinrin daadaa tẹ ẹ n wo yii ko ma si laye mọ o, ko si ti i sẹni to mọ ẹni to pa a lasiko ta a n kọ iroyin yii lọwọ. Ohun to kan daju ni pe awọn ọlọpaa ba oku ẹ ninu yara lẹyin ọjọ mẹta tawọn eeyan ko ti gburoo ẹ, ori ọmu rẹ mejeeji ko si nibẹ, mọ, ẹni to pa a si tun ge oju ara ẹ lọ nipinlẹ Delta to n gbe.

Blessing ni wọn pe orukọ obinrin naa, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29), ni. Ibi kan ti wọn n pe ni Mosogar, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ethiope, ni Delta, lo n gbe, oṣiṣẹ otẹẹli ni.

Alẹ ọjọ Satide to kọja ni wọn lo wale pẹlu ọkunrin kan ti wọn jọ wọ yara, nigba to si ṣe diẹ, awọn araale ri i pe ọkunrin naa jade ni yara Blessing pada,o ba tiẹ lọ.

Ṣugbọn lati alẹ ọjọ Satide naa ni ẹnikẹni ko ti ri Blessing ko jade sita mọ.

Nigba to di ọjọ Tusidee to tẹle e ti òórùn buruku n ti inu yara rẹ wa ni awọn araale too mọ pe wahala wa, nigba naa ni wọn fi to ọlọpaa leti, ti wọn si waa ja ilẹkun yara ọmọge ọhun.

Bi wọn ti wọle ni wọn ba a nihooho ọmọluabi, o ti ku. Oku Blessing ko pe mọ, wọn ni wọn ti ge ori ọyan rẹ mejeeji lọ, bẹẹ ni oju ara rẹ paapaa ko si nibẹ mọ.

Ṣa, iwadii awọn ọlọpaa ti bẹrẹ, nitori DSP Bright Edafe, Alukoro ọlọpaa ni Delta, ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o si lawọn ti gbe oku Blessing si mọṣuari, bẹẹ ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ bi ti iku rẹ yii ṣe jẹ o.

Leave a Reply