Oku sun rẹpẹtẹ nibi ija Amọtẹkun atawọn Fulani darandaran l’Ayetẹ

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, eeyan meje ni wọn lo padanu ẹmi wọn, ti ile meje ọtọọtọ si jona kanlẹ pẹlu dukia inu wọn lasiko ti ẹṣọ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtekun, ẹka ipinlẹ Ọyọ, fija pẹẹta pẹlu awọn Fulani darandaran niluu Ayetẹ, ni ipinlẹ naa.

Laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, nija ọhun waye nitori bi awọn Amọtẹkun pẹlu awọn ọdẹ ibilẹ ṣe ja si ọgangan ibi kan ti awọn Fulani darandaran atawọn Bororo kan maa n fara pamọ si ninu aginju igbo kan lagbegbe Aba Òkébì, nitosi ilu Ayetẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ.

ALAROYE gbọ pe irinajo awọn agbofinro ibilẹ wọnyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe gbọ pe inu aginju yii lawọn ajinigbe n lo fun iṣẹ laabi wọn. Wọn lẹnikan ti wọn ji gbe, ṣugbọn ti wọn pada fi silẹ lẹyin ti wọn ti gba miliọnu marun-un Naira lọwọ awọn ẹbi ẹ, lo tu aṣiri naa le wọn lọwọ.

 

Olugbe ilu Ayetẹ kan fidi ẹ mulẹ pe bi awọn Fulani ṣe ri awọn eleto aabo yii ni wọn gbe ere dà si i, ti awọn agbofinro naa si gbá fi yá wọn, wọn gba pe iṣẹ ọwọ wọn ni kò mọ́ ti wọn ṣe n sa lọ.

Ere ti awọn afurasi ọdaran yii pẹlu awọn agbofinro n sa ninu aginju yii lo mu ki awọn Fulani darandaran yooku to wa ninu igbo nla naa dide ija, ti awọn pẹlu awọn agbofinro si n dana ibọn funra wọn ya.

Gẹgẹ bi Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CSP Olugbenga Fadeyi, ati Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju ti i ṣe oludari ẹṣọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ọyọ ṣe fidi ẹ mulẹ, awọn ọlọpaa atawọn ikọ eleto aabo ipinlẹ Ọyọ ti gbakoso ibi ti wọn fi ṣe ibudo ija yii ati agbegbe ẹ lati dena itẹsiwaju ija naa.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Ile-ẹjọ to ga ju lọ da ẹjọ Buhari ti Malami pe ta ko ofin eto idibo nu

Faith Adebọla Ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa ti wọgi le ẹjọ ti Aarẹ …

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: