Ọkunrin to ba fipa b’obinrin sun ni Kaduna, wọn yoo fọ ọ ni ‘kinni’ ni

Bi ọkunrin kan ba lọọ fi tipatipa ba obinrin sun nibikibi ni ipinlẹ Kaduna, paapaa ti iru obinrin naa ko ti i ju ọmọ ọdun mẹrinla lọ, wọn yoo tẹ iru ọkunrin bẹẹ lọdaa ni, won yoo fọ ‘kinni’ rẹ, ti ko ni le fi nnkan-ọmokunrin ọhun ṣiṣẹ nibikibi mọ. Bo ba si waa jẹ obinrin lo fi tipatipa ba ọmọdekunrin sun, wọn yoo yọ ile ọmọ rẹ jade.

Ofin tuntun ti wọn ṣẹṣẹ ṣe ni ipinlẹ Kaduna ree, ana ode yii si ni Gomina Nasir El-Rufai fọwọ si i. Gomina naa ti n sọ tẹlẹ pe oun yoo ṣe ofin to le koko fawon afipa-bobinrin-sun ni ipinlẹ awọn, debii pe ko ni sẹni ti yoo fẹẹ huwakiwa bẹe mọ, nigba ti wọn ab ronmu loriiya t ole je awọn. Ohun to ṣokunfa ti wọn fi gbe ofin ọhun lọ sile igbimọ ree, ọsẹ to kọja yii lawọn ile igbimọ si fọwọ si i.

Bo tilẹ jẹ pe awọn kan ṣii n sọ pe ofin naa ti le ju, pe o le da nnkan mi-in silẹ lawujọ, Gomina El-Rufai ko wo oju wọn, o ni ohun to tọ si awọn ti wọn ba n fi ipa ba obinrin sun, tabi awọn ti wọn n ba ọkunrin sun, lawọn ṣe fun wọn yẹn.

Leave a Reply