Ọkunrin to wa latimọle ni Mariam n fi kula gbe igbo lọ fun tọwọ fi tẹ ẹ

Faith Adebọla

Maria Drissu lorukọ obinrin ẹni ọdun marundinlogoju yii, abiyamọ to n fọmọ lọmu lọwọ ni, ṣugbọn o ti dero ahamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ajọ NDLEA bayii, ibi to ti n fi kula ounjẹ gbe egboogi oloro ti wọn pe ni igbo lọ fun afurasi ọdaran kan to lọgba ẹwọn lọwọ ti tẹ obinrin naa, o ni wọn bẹ oun koun ba wọn ra a ni.

Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, Alukoro ileeṣẹ to n gbogun ti okoowo ati ilo egboogi oloro nilẹ wa, NDLEA, lo fi atẹjade nipa iṣẹlẹ yii ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde yii, o ni ọkan lara awọn ọgba ẹwọn to wa niluu Benin, nipinlẹ Edo, lọwọ ti ba obinrin naa.

Babafẹmi ṣalaye pe lọjọ Abamẹta, Satide, ti aṣiri Mariam tu, kula ounjẹ lo gbe dani, o ni ẹlẹwọn kan loun ba gbe ounjẹ ọhun wa, ounjẹ ilẹ Ibo ti wọn n pe ni Akpu lo wa ninu rẹ.

Ṣugbọn nigba ti ọkan lara awọn ẹṣọ ọgba ẹwọn fi ṣibi yẹ ounjẹ naa wo, wọn ri i pe nnkan kan tun wa nisalẹ kula naa, ti wọn di pamọ sinu lailọọnu funfun, nnkan ọhun si yatọ si ounjẹ Akpu ti wọn ri tẹlẹ. Lẹyin ayẹwo, akara tu sepo, wọn ri i pe igbo (marijuana) ni wọn di sinu lailọọnu naa.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti fi pampẹ ofin gbe iya ikoko, o di ọfiisi ajọ NDLEA, ibẹ lo ti jẹwọ fawọn agbofinro pe loootọ loun di igbo pamọ sisalẹ ounjẹ toun ra, o ni ẹlẹwọn to ran oun lounjẹ lo ni koun ba oun ra igbo bọ, bo si ṣe maa n ran oun niyẹn.

Babafẹmi ni iwadii ṣi n tẹsiwaju, o lafurasi ọdaran naa ti n ṣalaye ibi to ti n ra igbo ati ẹni to n ta a fun un, o si ti juwe ọdaran-mọran ẹlẹwọn to bẹ ẹ nigbo.

Laipẹ, gẹgẹ bi wọn ṣe wi, obinrin naa yoo dero ile-ẹjọ.

Leave a Reply