Ọkunrin yii fun ẹni to ya a lowo lọrun pa, o ni ko ma baa tu aṣiri oun ni 

Ifeanyi Ezinwa lorukọ ọkunrin yii, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) ni. Oun lo fun ọmọ kekere to ya a lẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira (100,000) lọrun pa nipinlẹ Anambra laipẹ yii. o ni nigba to n daamu oun ju loun pa a ko ma baa tu aṣiri oun faye.

Chukwuebuka Iloegbunam lorukọ ọkunrin ti Ifeanyi pa, mọlẹbi ni wọn. Aṣiri Chukwuebuka n bo pẹlu ṣọọbu to ti n ta ọja pẹẹpẹẹpẹẹ, ibẹ naa ni ọmọ ọdun mọkandinlogun naa (19) yii ti ṣa ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira jọ, to si ya Ifeanyi loṣu kejila, ọdun to kọja.

Ohun to ṣẹlẹ gan-an ti Ifeanyi fi yawo naa ni pe, o nawo ilu ti wọn ko si i lọwọ jẹ. Awọn ọja kereje ati isọ keekeeke to jẹ ti ilu ni wọn ni kọkunrin yii maa gba owo rẹ, ko si maa ṣakọsilẹ rẹ bo ṣe tọ, ko maa ko o si apo ilu lasiko to yẹ.

Ninu owo ilu ni Ifeanyi to niyawo kan ati ọmọ mẹta, ti yọ ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira, to na an bo ṣe fẹ.

Kawọn agba ilu to ni ko maa gba owo naa ma baa mọ ohun to ṣe lo jẹ ko lọọ ba Chukuwuebuka pe ko ya oun lowo naa, to si ṣadehun pe oun yoo da a pada fun un laipẹ rara.

Ninu oṣu kejila, ọdun 2020, ni Ifeanyi yawo naa gẹgẹ boun funra ẹ ṣe ṣalaye, o si loun yoo da a pada lọjọ kẹwaa, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021. Ṣugbọn kaka ko dawo ọhun pada, Ifeanyi ko da a pada fẹni to ya a lowo, nitori ko ni ọna mi-in to le gba sanwo naa, afi bi yoo ba tun mu ninu owo ilu, aṣiri yoo si pada tu naa ni.

Nigba ti owo naa n pẹ ju ti ko da a pada ni Chukwuebuka bẹrẹ si i da a laamu, o sọ fun Ifeanyi pe bi ko ba sanwo oun pẹlu bi oṣu mẹta ti ṣe gun ori rẹ yii, oun yoo fi ẹjọ rẹ sun awọn agbaagba ilu to fun un niṣẹ to n ṣe naa, iyẹn ko si ni i seso rere fun un.

‘’Bo ṣe n dunkooko mọ mi yẹn lo jẹ ki n pinnu pe mo maa pa a ni ki n le fi bo aṣiri ara mi. Mo ra burẹdi, mo si tọju ọbẹ to mu sinu rẹ. Mo pe Chukwuebuka  pe ko waa ba mi niyana Aguleri, mo sọ fun un pe mo ta ilẹ kan, mo si fẹẹ fun un lowo ti mo jẹ ẹ ninu owo naa, bo ṣe gun ọkada waa ba mi nibẹ ni nnkan bii aago mẹjọ-aabọ alẹ niyẹn.

‘’Mo mọ ọlọkada to gbe wa naa ri, mo si sọ fun un pe ko maa lọ ni tiẹ, ko ya emi ati Chukwuebuka lọkada ẹ nitori a fẹẹ jọ lọ sibi kan to jẹ ọna inu igbo. Ba a ṣe jọ n lọ ni mo n gba ọna ibi tawọn eeyan ki i saaba gba. Nigba to ya ni mo ni mo fẹẹ tọ, mo da ọkada naa duro, Chukwuebuka si duro de mi.

‘’Lojiji ni mo pada waa ba a pẹlu ọbẹ lọwọ, ṣugbọn o tete ri mi, o si gba ọbẹ naa lọwọ mi, o fi gun mi kaakiri ara gan-an. Nigba to ya ni apa mi ka a, mo bẹrẹ si i fun un lọrun titi ti mo fi fun un lọrun pa. Pẹlu ẹjẹ to wa lara mi yikayika ni mo sunkun lọ saarin igboro pe awọn ole lo da emi ati ẹ lọna, ati pe inu ewu lo wa, mi o mọ boya o maa ye.

‘’Wọn gbe mi lọ sọsibitu fun itọju, ṣugbọn ko pẹ ti awọn ọlọpaa fi waa mu mi, wọn ni ki n ṣalaye ohun ti mo mọ nipa iku Chukwuebuka. Igba ti mo ri i pe irọ mi ti ja patapata ni mo jẹwọ fun wọn.’’ Iyẹn ni alaye ti Ifeanyi ṣe.

O pada sọ pe oun ko mọ ọn mọ, o ni Eṣu lo wọnu ọpọlọ oun toun fi ṣe e. O ni kawọn ẹbi ati gbogbo ẹni tọrọ naa kan foriji oun.

Awọn ọlọpaa ti sọ pe yoo de kootu laipẹ ṣa, wọn ni yoo lọọ jẹjọ ipaniyan atawọn ẹsun mi-in to ba jẹ mọ ohun ti wọn n ba a fa lọwọ yii.

Leave a Reply