Ọkunrin yii gbe awọn ibẹta niyawo lọjọ kan naa, o ni wọn ti jọra wọn ju  

Keeyan gbeyawo kan, tabi ko fẹ obinrin meji ọtọọtọ papọ ti waye ri, ṣugbọn boya ni iru igbeyawo ti ọkunrin ti wọn porukọ ẹ ni Luwizo yii ti i waye ri, bo ba si waye ri, iru rẹ ko wọpọ rara, iyawo mẹta lo fẹ lẹẹkan naa, ibẹta si lawọn obinrin mẹtẹẹta naa, ọmọ baba atiya kan naa ti wọn bi lẹẹkan naa lo wọle ọkọ kan naa yii.

Luwizo, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ṣegbeyawo pẹlu awọn ibẹta ọhun lọjọ Satide, opin ọsẹ to pari oṣu Fẹbuari, ọdun yii, niluu Kalehe, ni Guusu Kivu. Lorileede Congo, nilẹ Afrika wa yii nigbeyawo alarinrin naa ti waye, ibẹ ni Natasha, Natalie ati Nadege tawọn mẹtẹẹta jẹ Ẹtaoko ti di aya rere lọọdẹ Luwizo.

Ọgbọn wo ni Luwizo da si i tawọn ibẹta naa fi gba pe ko di baale awọn mẹtẹẹta, lawọn eeyan n beere. Luwizo fẹnu ara ẹ ṣalaye fun iweeroyin AfriMax pe ọrọ naa ko ṣadeede waye, o ni ori ẹrọ ayelujara loun ti  ṣalapade ọkan ninu awọn ibẹta ọhun, awọn si jọ di ọrẹ lori fesibuuku, igba to ya lọrọ ifẹ yi wọ ọ, loun ba bẹrẹ si i wa obinrin naa lọ sile ẹ, ṣugbọn igbakuugba toun ba de ile naa, ọkan ninu awọn ibẹta naa lo maa n gba oun lalejo, oun o si da Taye mọ yatọ si Kẹhinde, tori awọn mẹtẹẹta jọra wọn bii imumu ni, ẹni kan naa loun ro pe oun n wa lọ lai mọ pe ẹni ọtọọtọ ni wọn, wọn kan jọra gidi ni. Bọjọ si ṣe n gori ọjọ lo di pe awọn mẹtẹẹta yofẹẹ fun ọkunrin naa.

Natalie, ọkan ninu awọn ibẹta naa sọ pe: “Ọjọ ta a kọkọ sọ fun un pe o gbọdọ fẹ awa mẹtẹẹta papọ ni o, ẹru ba a, aya ẹ ja. Ṣugbọn oun naa ti nifẹẹ awọn mẹtẹẹta, awa naa si nifẹẹ ẹ, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan n sọ pe nibo ni wọn ti n ṣeru ẹ, pe ko le ṣee ṣe ki ọmọ iya kan naa mẹta maa ṣajọpin ọkọ kan naa, ṣugbọn inu tiwa dun si i, lati kekere lawa mẹtẹẹta ti jọ n ṣajọpin awọn nnkan ta a ni.”

Ọkọọyawo naa sọrọ, o ni: “Mo fẹrẹ daku lọjọ ti wọn lawọn mẹtẹẹta lawọn maa fẹ mi papọ, mo bi wọn pe ewo lo n jẹ Natalie ninu wọn, tori oun ni mo kọkọ mọ, ṣugbọn wọn ni ko sẹni ti mi o ti ba pade ri ninu awọn, nigba to si jẹ ibẹta ni wọn, ti wọn o yatọ sira wọn, mo gba lati fẹ wọn papọ. Ko rọrun, tori awọn obi mi yari fun mi, wọn o fara mọ ọn, tori ẹ ni wọn o si ṣe wa sibi ayẹyẹ igbeyawo wa, ṣugbọn a dupẹ pe igbeyawo naa waye, o si larinrin gidi.”

Bayi ni Luwizo di ọkọ ibẹta lẹẹkan naa, ṣọọṣi kan lorileede naa ni wọn ti so wọn pọ, orukọ tuntun tawọn eeyan n pe Luwizo bayii ni: ‘Ọba Solomoni, alaya pupọ.’

Leave a Reply