Ija inu ẹmi ni ọkunrin ti ẹ n wo fọto rẹ yii, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Charles Thomson, n ba iya rẹ ja. O ni ajẹ ni iya oun, o si maa n yira pada di ejo lọwọ alẹ, bẹẹ ni ko fẹran oun rara. Ohun to jẹ koun gbe ija naa wa soju aye niyẹn, toun gun iya oun lọbẹ pa, ko ma baa ba toun jẹ loju aye.
Ṣọja ni Charles, ẹni ọgbọn ọdun ni, ṣugbọn o ti sa kuro loju ogun lapa Oke-Ọya ti wọn gbe e lọ. Kọmandi awọn ọlọpaa to wa ni Kaduna ni wọn ti foju ẹ han lọsẹ to kọja, lẹyin tọwọ ba a fun ti iya rẹ to gun lọbẹ pa.
Nigba to n ṣalaye bo ṣe ṣẹlẹ, Charles sọ pe ogun ọdun sẹyin ni baba oun ti sa lọ, to ko oun ati aburo oun si mama awọn lọwọ, ti ko wẹyin wo mọ. O ni ṣugbọn iya awọn ki i ṣe obinrin daadaa, ko nifẹẹ awọn ọmọ rẹ, afi ko maa sọrọ buruku nipa oun ati ikeji oun loju gbogbo aye.
Yatọ si eyi, Charles ni alagbara okunkun niya oun, bo ṣe n di ejo lo n pawọda. O ni eyi toun fi gun un pa yii, niṣe loun ri i ti ọmọ ọdun mẹwaa kan n sare yi i po.
O ni mama oun maa n poora, bẹẹ ni yoo tun yọ jade gurẹ nibi teeyan ko tiẹ lero, o ni ẹlẹyẹ pọnbele niya oun.
Nitori agbara to ni ti ko fi ṣe oun lanfaani yii, Charles ni ija loun ati iya maa n ja, lọjọ toun si gun un pa yii, awọn n ja loju aye ni, boun ṣe yọbẹ niyẹn toun gun un pa.
Charles ti wa lẹka to n gbọ ẹjọ ipaniyan, yoo tun jẹjọ lori bo ṣe sa loju ogun pẹlu, nitori wọn ko yọnda rẹ, oun lo sa lọ loju ogun.