Ọkunrin yii laye ti su oun, lo ba fẹẹ para ẹ n’Ikẹja, ọpẹlọpẹ LASEMA

Faith Adebọla, Eko

Bi ko ba jẹ ti ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA, ti wọn sare debi iṣẹlẹ ọhun, ti wọn si tete rọọṣi ọkunrin naa deleewosan ijọba ni, afaimọ ki Ọgbẹni kan ti wọn porukọ inagijẹ ẹ ni Ṣẹnṣẹma yii ma ti dẹni akọlẹbo pẹlu bo ṣe pinnu lati pa ara ẹ, o laye ti su oun.

Irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, la gbọ pe iṣẹlẹ naa waye nibudokọ kan ti wọn n pe ni National, loju ọna Maroṣe Sango si Oṣodi, lagbegbe Ikẹja.

Ọga agba ajọ LASEMA, Dokita Oluwafẹmi Oke-Ọsanyintolu, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ lawọn gba ipe pajawiri lori aago pe ọkunrin kan ti gun opo ti wọn so waya tẹlifoonu atijọ mọ, wọn lo ti de ori oke tente kawọn eeyan too fura si i, ni wọn ba bẹrẹ si i bẹ ẹ pe ko ma para ẹ, ṣugbọn wọn lọkunrin naa laye ti su oun, ki wọn foun silẹ. Eyi lo mu ki wọn tẹ ileeṣẹ LASEMA laago.

Oluwafẹmi ni kiakia lawọn oṣiṣẹ ajọ naa ti sare debi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn ki wọn too debẹ, Ṣẹnṣẹma ti bẹ latori opo naa, eti gọta to wa lẹgbẹẹ ọna reluwee to bẹ si, o si fara pa yannayanna, bo tilẹ jẹ pe o ṣi n mi.

Wọn ni ọgbẹ nla kan wa nibi ẹsẹ ẹ, o si da bii ẹni pe ọrun ẹsẹ naa ti rọ, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ajọ naa fun un ni itọju pajawiri ki wọn too fi ọkọ gbokuu-gbalaaye (ambulansi) wọn gbe e lọ sọsibitu jẹnẹra lo wa n’Ikẹja.

Oluwafẹmi fi kun ọrọ rẹ pe akiyesi tawọn ṣe nigba ti wọn n tọju ọgbẹni naa ni pe o ti muti yo, ọti lile lo si mu. Wọn tun yẹ ifunpa ẹ wo, wọn ri i pe o ti ga, eemi rẹ ko si delẹ mọ, afẹfẹ ọsigin (oxygen) ni wọn so mọ ọn nimu ti wọn fi gbe e dele iwosan ọhun.
Ọga agba LASEMA dupẹ lọwọ awọn araalu to tete pe wọn lori aago, o si rọ kaluku lati tubọ wa lojufo sawọn eeyan ati ohun to ba n ṣẹlẹ ni sakaani wọn.

Leave a Reply