Ọla ko sinu ‘tanki’ omi n’Idiroko, nitori ki wọn ma baa ri i mu lẹyin to jale

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Oṣu to kọja yii ni wọn da ọmọkunrin tẹ ẹ n wo yii, Ọla Adeoye, duro nileeṣẹ Owoyemi Super Store, n’Idiroko, nipinlẹ Ogun. Afi bo ṣe tun gba ibẹ lọ loru ọjọ kẹta, oṣu kẹfa yii, to lọọ jale. Ki wọn ma baa ri mu nigba taṣiiri fẹẹ tu, niṣe lo sa wọnu tanki omi to wa nileeṣẹ naa lọ, to dakẹ jẹẹ sibẹ.

Ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) lọmọkunrin yii, o gba ori bakoni aja keji ileeṣẹ naa wọ ọfiisi ọga agba, o tu ibẹ kalẹ finni-finni pẹlu igbiyanju lati fọ irin ti wọn maa n kowo si (safe). O ti pitu ọwọ rẹ lọfiisi naa daadaa ki ipe too de etiigbọ DPO teṣan Sango.

CSP Godwin Idehai ti i ṣe DPO teṣan naa ko awọn eeyan rẹ lẹyin lati mu awọn ole to pitu naa.

Lẹyin tawọn ọlọpaa tu gbogbo ibẹ ti wọn ko ri ole to fọ ọfiisi yii, wọn pada ri Ọla Adeoye nibi to sa si ninu agba omi to wa nileeṣẹ naa, bi wọn ṣe mu un ṣinkun niyẹn.

Nigba ti wọn fọrọ wa a lẹnu wo, o jẹwọ pe oṣiṣẹ ile ileeṣẹ naa loun tẹlẹ. O ni oṣu karun-un to kọja yii ni wọn ṣẹṣẹ da oun duro pe koun ma wa mọ. Bo ṣe tun waa jẹ ibi ti wọn ti le e naa lo tun ti waa jale ni ko ri esi gidi kan ti yoo fọ si i.

O ṣaa ti wa lakata awọn ọlọpaa bayii, bi wọn ba si ti pari iwadii ni wọn yoo ṣewe kootu fun un gẹgẹ bi CP Edward Ajogun ṣe sọ.

Leave a Reply