Olugbenga Ale di olori awọn oṣiṣẹ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

Gomina ipinlẹ Ondo Rotimi Akeredolu ti kede Ọgbẹni Richard Ọlabọde Ọlatunde gẹgẹ bii akọwe iroyin rẹ.

Ilu Ọwọ ti i ṣe ilu abinibi Gomina Akeredolu funra rẹ ni Ọlabọde ti wa, oun ni akọroyin fun ileesẹ redio aladaani kan to wa niluu Ileṣa, nipinlẹ Ọsun, ko too gba ipo Oludamọran fun gomina lori ọrọ iroyin ori ẹrọ ayelujara lọdun 2019.

Ipo yii naa lo si di mu titi ti wọn fi kede rẹ gẹgẹ bii akọwe iroyin gomina lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ẹni keji ti wọn tun kede iyansipo rẹ ni Oloye Olugbenga Ale to jẹ olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina.

Ọmọ ilu Ọwọ kan naa pẹlu gomina ni Ale, ko ju bii ọdun diẹ to fẹyinti kuro lẹnu iṣẹ ijọba nigba ti wọn kọkọ yan an sipo yii kan naa lọdun mẹrin sẹyin.

 

Leave a Reply