Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Bi obinrin kan tawọn ọlọpaa forukọ bo oun atọmọ rẹ laṣiiri l’Abẹokuta ba mọ pe wahala ni Ọladapọ Akinọla, ọkọ to fẹ bayii lẹyin to ti fẹ ọkunrin kan tẹlẹ yoo jẹ foun atọmọ naa ni, o daju pe ko ni i fẹ ẹ, nitori Ọladapọ ti fi kinni to fi n ba obinrin naa sun, han ọmọ tiyaa gbe waa fẹ ẹ leemọ bayii. O ti ba ọmọ ọdun marun-un naa sun, o si ti fadi ẹ ya.
Ẹni ọdun mọ́kàndínlógoji (39) ni Ọladapọ Akinọla. Ṣokori, l’Abẹokuta, lo n gbe pẹlu ọmọ
yii ati iya rẹ to fẹ́.
Afi bo ṣe di Mọnde, ogunjọ, oṣu kẹsan-an yii, ti iya ọmọ naa n wẹ fun un to si ri ẹjẹ labẹ ọmọ kekere yii. Iya beere pe ki lo fabẹ ṣe, ọmọ naa si dahun pe ọkọ iya oun lo ki kinni rẹ bọ toun.
Iyawo Ọladapọ ko pariwo, teṣan ọlọpaa Adigbẹ, l’Abẹokuta, lo gba lọ. O sọ ohun to sọ ṣẹlẹ fun wọn nibẹ, DPO ibẹ, SP Fatobẹru Oyekanmi si ran awọn ikọ rẹ lati lọọ mu ọkunrin to n ba iya atọmọ kekere lo pọ naa wa, wọn si gbe e de teṣan lọwọ kan lọjọ Mọnde naa.
Nigba to n ṣalaye fawọn ọlọpaa, Ọladapọ jẹwọ pe loootọ loun ba ọmọ ọdun marun-un naa lo pọ, ṣugbọn ko sọ idi kan pato to fi huwa aitọ yii.
Wọn gbe ọmọ to ba ṣerekere lọ sọsibitu fun itọju, wọn si taari ọkunrin yii si ẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn to n ṣe ọmọde ṣakaṣaka.
Awọn ọlọpaa gba awọn iya nimọran pe ki wọn maa mojuto awọn ọmọ wọn obinrin gidi, nitori awọn abanilayejẹ ọkunrin pọ kaakiri.