Florence Babaṣọla
Gbogbo awọn ti wọn wọle sinu sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọṣun to wa ni Abere, niluu Oṣogbo, laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni wọn ba ọmọkunrin kan, Adebọwale Ọladayọ, lẹnu geeti, akọle nla kan lo gbe siwaju, ninu rẹ lo si ti ke si Gomina Gboyega Oyetọla lati fun oun niṣẹ.
Ọladayọ, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, lo kọ ọ sinu akọle naa pe ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ, nipinlẹ Ọṣun, loun, oun si nilo iṣẹ lati le jẹ baba rere ninu ile.
Ninu akọle naa lo ti ni akẹkọọ-gboye ni ẹka ti wọn ti n kẹkọọ nipa ibagbepọ ọmọniyan (Social Studies Education) ni Fasiti Ado-Ekiti loun, oun si n kẹkọọ ifimọkunmọ lọwọ nipa bi a ṣe n yanju aawọ ni Fasiti ilu Ilọrin.
O ke si Gomina Adegboyega Oyetọla pe oun nilo iṣẹ ni kiakia.