Ọladeji to fipa ṣe ‘kinni’ fọmọ ọdun mọkanla dero ẹwọn l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Kọrọ, ni palapala ile akọku kan, ni wọn lọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogoji yii, Ojo Ọladeji, ti fipa ki ọmọ ọlọmọ kan tọjọ ori rẹ ko ju mọkanla lọ mọlẹ, to fipa ba a sun, ṣugbọn gbangba ile-ẹjọ l’adajọ ti paṣẹ pe ki wọn lọọ fi i pamọ sahaamọ ọgba ẹwọn na.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni wọn wọ afurasi ọdaran naa dele-ẹjọ Majisreeti kan to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, lori ẹsun ifipabanilopọ ati iwa to le da alaafia ilu ru ti wọn fi kan an.

Agbefọba, Inpẹkitọ Lucky Ihiehie, to ṣalaye bi ẹsun naa ṣe jẹ ni kootu ọhun sọ pe ọjọ keje, oṣu kẹjọ, ọdun yii, lafurasi ọdaran yii huwa buruku naa, o ni niṣe lo tan ọmọbinrin ọhun lọ sinu ile akọku kan ni Meiran, lagbegbe Alagbado, lo ba ki ọmọ naa mọlẹ, o si fipa ba a laṣepọ.

O ni iwa ti Ojo hu yii buru gidi, o ta ko isọri kẹtadinlogoje (137) iwe ofin iwa ọdaran ti ọdun 2015 tipinlẹ Eko n lo. O ni ijiya ẹwọn gbere wa lara idajọ tiwee ofin naa la kalẹ fun iru ẹṣẹ yii.

Wọn beere boya Ojo jẹbi abi ko jẹbi, oun naa si fẹsi pe oun o jẹbi pẹlu alaye.

Adajọ A. O. Layinka ni ko ti i saaye fun alaye kankan, oun o si le faaye beeli silẹ fun afurasi ọdaran yii, o ni ki wọn taari ẹ si ọgba ẹwọn Kirikiri, ibẹ ni ko ti lọọ maa gbatẹgun titi di ọjọ igbẹjọ to kan.

Leave a Reply