Nitori ọrọ ti ko to nnkan, Ọlamilekan luyawo ẹ pa l’Ode-Rẹmọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

  Iwadii gidi ti bẹrẹ lori idi ti Ọlamilekan Mojiyagbe, ẹni ọdun mẹrinlelogun pere (24), ṣe bẹrẹ si i lu iyawo ẹ, to si ṣe bẹẹ lu u pa lọjọ kẹta, oṣu kọkanla yii, nile wọn to wa lagbegbe Oke-Ọla, l’Ode-Rẹmọ, nipinlẹ Ogun.

Niṣe ni Ọlamilekan tilẹkun mọra ẹ pẹlu iyawo naa ti wọn pe ni Ṣeun Majiyagbe, to si bẹrẹ si i lu u lai jẹ ki ẹnikẹni wọle lati gba a silẹ.

Awọn araale n gbọ ariwo iyawo naa bi ọkọ rẹ ti n lu, wọn fẹẹ gba a silẹ, ṣugbọn wọn ko rọna wọle nitori Ṣeun ti tilẹkun pa. Bi wọn si ti bẹ ẹ pe ko ṣilẹkun to, ko da wọn lohun.

Nigba to taku ti ko ṣilẹkun, ti lilu ọhun ko si duro lawọn eeyan pe teṣan ọlọpaa Ode-Rẹmọ, lawọn yẹn ba lọ sibẹ ni nnkan bii aago mẹta ọsan ti wọn fi iṣẹlẹ naa to wọn leti.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi to fiṣẹlẹ naa sita ṣalaye pe titipa naa lawọn ọlọpaa to lọ sibẹ ṣi ba ilẹkun, wọn fipa ja a wọle ni, nitori ọkunrin to n luyawo ẹ naa tun kọ lati ṣilẹkun fun wọn.

Nigba tawọn agbofinro wọle, obinrin to n lu naa ti wa ninu agbara ẹjẹ, ọkọ rẹ ti fi lulu ṣe e leṣe, ko si mọ ibi to wa mọ.

Awọn ọlọpaa sare gbe e lọ sọsibitu Jẹnẹra Iṣara- Rẹmọ, ṣugbọn awọn dokita sọ pe o ti ku.

Bayii ni wọn fọwọ ofin mu ọkọ to luyawo ẹ pa naa, wọn ju u si gbaga.

Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, ti ni ki wọn gbe e lọ sẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn apaayan fun iwadii to lagbara, wọn yoo si gba ibẹ gbe e lọ si kootu laipẹ rara.

 

Leave a Reply