Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Arakunrin ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Ọlawale Samuel, ọmọ agboole Amulegbọlọla, niluu Ogbomọsọ, nipinlẹ Ọyọ, ni adajọ A. Y Ameenullahi, ti sọ sẹwọn oṣu mẹfa fẹsun pe o lọọ ji ewurẹ gbe lagbegbe Gari-Alimi, niluu Ilọrin, to lọọ ta a ni ọja Ọba.
Insipẹkitọ Ọdẹrinde Abideen, lo wọ afurasi ọdaran naa lọ si ile-ẹjọ fẹsun ole jija, to si ta ko abala ọọdunrun le mọkandinlogun (319), ninu iwe ofin ilẹ wa.
Ọlawale gba pe lootọ lo jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an. Eyi lo mu ki
Onidaajọ, A.Y Ameenullahi paṣẹ pe ko lọọ sẹwọn oṣu mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara tabi ko san ẹgbẹrun lọna ogun Naira (#20,000) gẹgẹ bii owo itanran.