Adewale Adeoye
Ni bayii, awọn alaṣẹ ijọba orileede Amẹrika, ti fọwọ ofin mu ọmọ orileede Naijiria kan, Ọgbẹni Yọmi Jones Ọlayẹye, ẹni tawọn eeyan mọ si Sabbie of Lagos, ẹni ogoji ọdun. Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ni wọn fọwọ ofin mu un bo ṣe de si papakọ-ofurufu John F Kennedy International Airport, to wa niluu New York City, lorileede Amẹrika lọhun-un. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe oun atawọn ọrẹ rẹ mẹta kan ti wọn lawọn n wa bayiiṣe gbaju-ẹ iyẹn Yahoo-Yahoo fun ijọba orileede naa lọdun 2020, lasiko ajakalẹ arun Korona, iyẹn COVID-19.
ALAROYE gbọ pe ṣe ni afurasi ọdaran ọhun da ọgbọn buruku kan, o pe ara rẹ ni ọmọ orileede Amẹrika, o si beere fun owo iranwọ lọwọ ijọba orileede naa. Lasiko ọhun lo lọọ ṣi akanti kan sorileede ọhun, ibẹ si ni ijọba orileede Amẹrika n fowo naa ranṣẹ si. Lara awọn ilu to ti gbowo iranwọ naa ni: Montana, Maine, Ohio ati Washington D.C. Apapọ owo iranwọ ti wọn lo gba lọwọ ijọba jẹ miliọnu mẹwaa dọla owo ilẹ okeere.
Oga agba ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ kan to wa nidii ẹjọ naa, Ọgbẹni Andrew Murphy, ti ni awọn n ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun lọwọ, awọn si maa ba Ọlayẹye atawọn ọrẹ rẹ ṣẹjọ b’ọwọ ba tẹ awọn yooku rẹ. Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu yii, ni wọn kọkọ foju rẹ bale-ẹjọ giga kan lorileede naa, ti wọn si tun sun igbẹjọ siwaju di ọjọ mi-in bayii.
Ẹwọn ogun ọdun ni ofin orileede naa sọ pe ẹni to ba jẹbi ẹsun Yahoo-Yahoo maa lo lọgba ẹwọn.