Ọlayinka lẹdi apo pọ pẹlu babalawo, ni wọn ba lu oniṣowo kan ni jibiti miliọnu mejidinlọgbọn naira n’Ilọrin

Stephen Ajagbe, Ilorin

Afurasi kan, Ọlayinka Monjo, to n gbe Ararọmi, lagbegbe Oko Olowo, niluu Ilọrin, ti n gbatẹgun lọgba ẹwọn fẹsun pe o lẹdi apo pọ pẹlu babalawo kan to n jẹ Baba Onikẹkẹ lati lu oniṣowo nla kan, Ṣhittu Bisiriyu, ni jibiti miliọnu mejidinlọgbọn naira.

Akọsilẹ ileeṣẹ NSCDC ṣalaye pe Ṣhittu lọọ ba Monjo fun iranlọwọ lati mu ki okoowo rẹ gberu ju bo ṣe wa lọ. Ni Monjo ba ni ko lọọ ba Baba Onikẹkẹ, ẹni to ti na papa bora bayii lẹyin to gba owo tabua lati ba oniṣowo ọhun ṣe ohun to n fẹ.

Laarin oṣu kọkanla, ọdun 2019, si oṣu kẹsan-an, ọdun 2020, ni Baba Onikẹkẹ fi n gba owo naa diẹdiẹ lọwọ Ṣhittu, titi to fi wọ miliọnu mejidinlọgbọn naira, sibẹ ko si aṣeyọri kankan ti babalawo naa ri ṣe lori iṣẹ tiyẹn gbe fun un.

Amofin Ajide Kẹhinde to ṣoju NSCDC nile-ẹjọ ni ki wọn gbe Ọlayinka sahaamọ nitori pe awọn ṣi n wa Baba Onikẹkẹ to sa lọ.

Adajọ Muhammed Ibrahim gba ẹbẹ agbefọba naa wọle, o ni ki wọn gbe afurasi naa lọ sọgba ẹwọn Oke-Kura, bakan naa lo fun awọn agbofinro laṣẹ lati wa afurasi keji (Baba Onikẹkẹ), kan, ki wọn si gbe e.

Adajọ tun paṣẹ fawọn NSDCD lati lọọ ti ile ti Onikẹkẹ n lo gẹgẹ bii ojubọ lati lu jibiti naa. O sun ẹjọ si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun yii.

Leave a Reply