Ọlayinka ko kokeeni sinu ike ata gbigbẹ, o n gbe e lọ si Canada, papakọ ofurufu Ikẹja lọwọ ti tẹ ẹ

Faith Adebọla, Eko

Adewuyi Ọlayinka lorukọ ọkunrin yii, ori kanta SAHCO ti wọn ti n yẹ ẹru to fẹẹ gbe lọ siluu oyinbo wo ni laṣiiri ẹ ti tu pe ki i ṣe agbo ati ata gbigbẹ nikan lo wa ninu lailọọnu funfun to gbe dani, egboogi oloro ti wọn n pe ni kokeeni lo tọju sibẹ, to fẹẹ gbe sọda.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ọwurọ ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, lọwọ ba afurasi ọdaran yii ni papakọ ofurufu Muritala Mohammed to wa n’Ikẹja, nipinlẹ Eko.

Ṣe bawọn kan ṣe mọ nnkan i tọju lawọn mi-in mọ ọn wa, wọn lọkunrin naa ti kọja lawọn ibi ayẹwo meji, ti ko sẹni to fura si ẹru to wa lọwọ ẹ rara, tori lailọnu funfun lo fi we ẹru naa, rekete lawọn eeyan si n wo awọn itakun ati eepo igi gbigbẹ to di papọ sinu lailọọnu naa bii ẹni pe eroja agbo ni wọn, lai mọ pe jagunlabi ti tọju ẹru ofin saarin agbo to n gbe kiri.

Ọgbọn kan naa lo da si ẹru keji, ike ti wọn fi n rọ omi lo rọ ata gbigbẹ si, ata gbigbẹ lo han yipo ike naa, ṣugbọn ẹru egboogi lẹbulẹbu funfun wa laarin ike naa lọhun-un, kokeeni ni wọn pe awọn lẹbulẹbu funfun naa.

Adele Ọga agba ajọ to n gbogun ti gbigbe ati ilo egboogi oloro, NDLEA, Ahmadu Garba, sọ pe nigba ti wọn gbe egboogi oloro ti ọkunrin naa fẹẹ gbe kọja sori oṣuwọn, giraamu ẹgbẹta o le aadọta lo wọn (650 grammes).

Nigba ti wọn ni ki Ọlayinka ṣalaye bi tọrọ kokeeni laarin agbo ati ata gbigbẹ ṣe jẹ, wọn lo jẹwọ pe orileede Canada loun n gbe lẹbulẹbu ọhun lọ, o loun fẹẹ lọọ ta a ni, wọn lo ni akọja ewe oun ree, bo tilẹ jẹ pe oun ti maa n ta kinni naa labẹle tẹlẹ, igba akọkọ toun fẹẹ gbe e kọja niyi.

Ṣa, Ọgbẹni Garba lawọn ti fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran yii, awọn agbofinro si ti n ba iwadii lọ lori ọrọ ẹ, wọn loun ati ẹsibiiti ti wọn ba lọwọ rẹ maa to fara han ni kootu.

Leave a Reply