Ole ki i deede ja laafin, afi ti ọba ko ba gbọ ikilọ-Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn

Lati igba ti rogbodiyan to ṣẹlẹ nipinle Eko, to pada waa ran kaakiri awọn ipinle mi-in ni Naijiria ti ṣẹlẹ ni awuyewuye ti n lọ kaakiri lori ọrọ naa. Awọn eeyan bara jẹ lori bawọn ṣọja ṣe kọ lu awọn ọdọ to n wọde nibi ti wọn ko ara papọ si ti wọn si dana ibọn fun wọn. Awọn eeyan binu nitori bi ẹmi ati dukia ṣe ṣofo. Eyi to kọ awọn araalu lominu ju ni bi awọn janduku ṣe wọ aafin ọba ilu Eko, Rilwan Akiolu, lọ, ti wọn si gbe ọpa ọba naa pẹlu awọn nnkan olowo iyebiye mi-in ti wọn ji laafin.

Iṣẹlẹ ọpa aṣẹ ọba ti wọn gbe yii lo mu akọroyin ALAROYE, FLORENCE BABAṢỌLA, tọ Araba ilu Osogbo, Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn, lọ lati sọrọ nipa ohun to le tidi ẹ yọ.

ALAROYE: Ki ni pataki ọpa-aṣẹ lọwọ ọba nilẹ Yoruba?

Oloye Ẹlẹbuibọn: Lakọọkọ, oriṣiiriṣii ni ọpa-aṣẹ, bi a ṣe ni ojulowo ọpa-aṣẹ, bẹẹ la ni ọpa-aṣẹ to wa fun ayẹyẹ (Ceremonial), ohun lawọn ọba maa n gbe ranṣẹ teeyan ba n ṣe oye tabi inawo, oun ni wọn fi maa n rọpo ara wọn nibẹ, ọtọ ni ọpa-aṣẹ ti ọba fi n jẹ ọba. Ni ilẹ Yoruba, aafin jẹ ibi-ọwọ (sacred place), ibẹ ni wọn ṣe gbogbo awọn nnkan iṣẹda ilu lọjọ si, o da bii orirun, o da bii ipọnri, ki i ṣe pe ọpa-aṣẹ nikan lo wa laafin to lagbara, to maa n fun ọba laṣẹ, ibẹ ni aṣẹ wa, awọn oriṣa ti wọn tẹ ilu yẹn do, ti wọn si n bẹ niluu yẹn wa nibẹ. Ọpa aṣẹ jẹ nnkan to n mu ọba niyi, to si n fun ọba ni aṣẹ.

ALAROYE: Ti wọn ba wa gba ọpa-ạṣe lọwọ ọba, ti wọn gbe e lọ, ki ni itumọ rẹ?

Oloye Ẹlẹbuibọn: Bii igba ti wọn fẹẹ sọ eeyan di yẹpẹrẹ, ti wọn taayan labuku ni, tori wọn ki i gba aṣẹ lọwọ ọba lasan, bẹẹ ni wọn ki i yọ ọba nipo lasan, ti wọn ba fẹẹ yọ ọba nipo, awọn ijoye le sọ pe ki ọba ṣi igba-iwa wo, ko fi aye silẹ fun awọn. Ti ọba ba n ṣe nnkan ti ko dara, o ni bi awọn obinrin ilu ṣe le kora jọ lai wọ aafin, ti wọn aa maa kọrin lati fi ẹhonu han pe awọn ko fara mọ nnkan ti ọba awọn n ṣe. Ṣugbọn bi ti ọba yii ṣe rin, o da bii ẹni pe ejo lọwọ ninu, o da bii ẹni pe ọta ti wa ninu ile. Fun apẹẹrẹ, ti eeyan ba fọ ile ọba, ikan to n gbe ninu ọgan, ọkẹ aimọye awọn eerun ni wọn a maa ja ẹni naa jẹ lọwọ, ko ni i rọrun lati debi ti ọba ikan wa, bi aafin ṣe ri niyẹn. Ọba ti ni ọta laarin adugbo, laarin awọn to yi i ka, bi ko ba ri bẹẹ, o ṣoro lati deede ku giiri wọ aafin bẹẹ yẹn, ole ile lo maa n ṣilẹkun fun tita. Ọba gan-an ni lati kiyesi iwa rẹ, iwa rẹ o daa laduugbo yẹn, ko lọrẹẹ lara awọn abẹṣinkawọ atawọn ẹmẹwa rẹ.

ALAROYE: Ṣe o niye ọjọ ti ọpa-aṣẹ waa gbọdọ lo nita?

Oloye Ẹlẹbuibọn: Ko gbọdọ pẹ, ṣugbọn eyi ti wọn gbe lọ yẹn, ọpa-aṣẹ ayẹyẹ ni. Ki i ṣe ojulowo ni wọn gbe lọ, mo ri aworan yẹn pẹlu ẹni to n gbe e lọ. Ẹni to gbe e yẹn ti fi ara rẹ ṣepe bẹẹ yẹn, aye rẹ ti bajẹ, gbogbo nnkan lo le ṣẹlẹ si i. Nigba atijọ, ọba maa n difa ọrọọrun, wọn aa ti ri ewu tabi ajalu to ba n bọ. Ole ki i deede ja laafin, to ba ṣẹlẹ, o ṣee ṣe ko jẹ pe  ọba kọti ọgbọnin sikilọ, iyẹn lo maa n fa ki laluri ṣẹlẹ si ọba.

ALAROYE: Nigba ti wọn gbe ọpa-aṣẹ yẹn tan, wọn juna si gbogbo aafin, ki lo le ṣẹlẹ bayii?

Oloye Ẹlẹbuibọn: O buru jai o, tiru iyẹn ba ṣẹlẹ, o si lewu pupọ fun ilu paapaa.

ALAROYE: Ni bayii ti wọn ti bẹ awọn alalẹ lọwẹ si awọn to gbe ọpa-aṣẹ, ki lero yin nipa rẹ?

Oloye Ẹlẹbuibọn: Ti awọn ọba yẹn o ba ṣe nnkan ti ko dara tẹlẹ, awọn alalẹ aa dahun, ti wọn ba n bọ wọn deedee, ṣugbọn to ba jẹ pe ọjọ ogun ni wọn ṣẹṣẹ n wa wọn, o le diẹ.

Leave a Reply