Ole kọju ija sọlọpaa n’Ikẹnnẹ, lẹni kan ba dero ọrun ninu wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Kutu hai laago marun-un idaji ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, lawọn ole kan gbegi dina tibọn-tibọn loju ọna Ọlabiro, n’Ikẹnnẹ, ipinlẹ Ogun, wọn si n jale laduugbo naa. Eyi ni wọn n ṣe lọwọ tawọn ọlọpaa fi de, lawọn ole ba kọju ija sawọn to fẹẹ di wọn lọwọ, ni wọn ba n yinbọn sawọn ọlọpaa lákọlákọ.

O to ọgbọn iṣẹju ti ikọ adigunjale yii atawọn ọlọpaa teṣan Ikẹnnẹ fi n yinbọn sira wọn gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro wọn ṣe wi. O ni lopin ija naa ni ibọn ọlọpaa ba ole kan, ibọn naa lo si pa a.

Iku ole yii lo mu awọn yooku rẹ sa, ṣugbọn pẹlu ọta ibọn lawọn naa juba ehoro.

Ibọn ilewọ ibilẹ kan, ọta ibọn ti wọn ko ti i yin ateyi ti wọn ti yin pẹlu foonu kan ni wọn ba lara adigunjale to ku naa.

Ọga ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Awolọwọ Ajogun, paṣẹ fawọn ọlọpaa to koju ole yii pe ki wọn wa awọn to sa lọ naa ri, ki wọn le koju ofin, bẹẹ lo yin wọn fún bi wọn ṣe ko awọn adigunjale naa loju.

Ajogun ni kawọn ọdaran ro o daadaa ki wọn too waa ṣọṣẹ nipinlẹ ogun, nitori ko si bi wọn yoo ṣe rin in tọwọ ofin ko ni i to wọn.

Leave a Reply