Ole ku soju ija ni Ṣagamu, awọn ọlọpaa lo yinbọn pa a

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta                                

  Ọjọ kẹfa, oṣu kejila, ti i ṣe ọjọ Aiku, ọsẹ yii, ni adigunjale kan padanu ẹmi ẹ loju ọna marosẹ Ṣagamu si Ikẹnnẹ, awọn ọlọpaa lo yinbọn pa a nibi to ti n ja awọn eeyan lole lọwọ pẹlu awọn ẹgbẹ ẹ.

Awọn kan ni wọn pe ọlọpaa ni ẹkun Ikẹnnẹ, pe awọn adigunjale n ṣọṣẹ laarin ile-epo ati ileeṣẹ kan to wa loju ọna marosẹ naa, ti wọn n fi  ibọn da awọn eeyan lọna, ti wọn n gba tọwọ wọn.

DPO teṣan Ikẹnnẹ, CSP Ndoukauba Onuma, ko awọn ikọ rẹ lẹyin lọ sibi ti idigunjale naa ti n lọ lọwọ, niṣe lawọn ole naa ko wọn loju nigba ti wọn debẹ. DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, fidi ẹ mulẹ pe awọn ole naa ko sa fọlọpaa, niṣe ni wọn doju ibọn kọ awọn agbofinro, ti wọn jọ n finna mọra wọn.

Loju ija naa ni ibọn ti ba ọkan ninu awọn ole yii, to si ṣe bẹẹ dagbere faye, nigba tawọn yooku ẹ sa lọ pẹlu ọta ibọn to ba wọn.

Ibọn kan, mọto ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan to ni nọmba KNN 84 TD, tawọn ole naa ja gba lọwọ ẹni to ni in lawọn ọlọpaa ri gba lọwọ wọn.

Imọran ti waa lọ sọdọ awọn ọlọsibitu ati ile elegboogi, pe bi wọn ba ri ẹni to n wa ibi ti wọn yoo ti ba a yọ ota ibọn lara rẹ, ki wọn jẹ ki ọlọpaa gbọ, nitori o ṣee ṣe ko jẹ ọkan lara awọn atilaawi ti ibọn ba nibi ti wọn ti kọju ija sọlọpaa naa ni.

Bakan naa ni CP Edward Ajogun, fi ọkan awọn eeyan ipinlẹ Ogun balẹ bọdun ṣe n sun mọle yii, o ni aabo ẹmi ati dukia wọn jẹ awọn ọlopaa logun, awọn yoo si maa ṣiṣẹ awọn lọ lai ko aarẹ ọkan.

Leave a Reply