Ole lawọn ọlọpaa n fi igi ti wọn n gbe dina lalaalẹ yii ja o – Mista Makaroni

Faith Adebọla, Eko

 Gbajugbaja adẹrin-in poṣonu ilẹ wa to tun maa n ja fẹtọọ ọmọniyan, Ọgbẹni Debọ Adedayọ, tawọn eeyan mọ si Mista Makaroni ti sọ pe niṣe lawọn ọlọpaa n fi igi ti wọn n gbe dina lalaalẹ ja awọn ọlọkọ lole, o ni niṣe ni wọn n gbowo lọwọ wọn, ti wọn si n ko wọn nifa.

Makaroni sọrọ yii ninu atẹjade kan to fi soju opo ayelujara rẹ lori ikanni tuita (tweeter) l’Ọjọruu, Wẹsidee yii.

O lawọn ọlọpaa naa daju, tori wọn o tiẹ naani bi nnkan ṣe nira fawọn eeyan to lasiko ọwọngogo ọja yii, niṣe ni wọn tun sọ ara wọn di agbalọwọmeeri, ti wọn n ko awọn onimọto ati araalu nifa lalaalẹ lawọn ibi ti wọn n ba duro si, ti wọn lawọn n ṣe ayẹwo ọkọ.

Bayii ni Makaroni ṣe sọrọ ọhun: Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria pẹlu ibudo ayẹwo mọto ti ko bofin mu, paapaa lalẹ. Niṣe ni wọn n fagidi gbowo lọwọ awọn ọmọ Naijiria, wọn aa tun halẹ mọ wọn, awọn ẹni ẹlẹni toju wọn ti ri mabo ki wọn too ri tọrọ kọbọ ti wọn pa. Pẹlu gbogbo ohun toju n ri lasiko yii, ṣe o tun yẹ kawọn ọlọpaa tun jade lati maa gba lara owo taṣẹrẹ to wa lọwọ awọn eeyan. Iwa ailojuti gbaa leyi o!

Bẹẹ ni Debọ wi.”

Leave a Reply