Ole ti mo n ja ki i ṣoju lasan, wọn fi ṣe mi ni-Benjamen

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ọkunrin ẹni ọdun mejilelogoji kan to porukọ ara rẹ ni Benjamen lọwọ tẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja, nibi to ti n fọ ṣọọbu oniṣọọbu niluu Akurẹ.

Benjamen to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kogi ati ọrẹ rẹ kan, Joseph, ni wọn mu pẹlu ọpọlọpọ ẹru ole ti wọn ji ko lagbegbe oju ọna marosẹ Ondo ni nnkan bii aago marun-un idaji ọjọ ta a n sọrọ rẹ yii.

Ninu alaye ti oun funra rẹ ṣe fun akọroyin wa nigba ta a n fọrọ wa a lẹnu wo, ilu Okitipupa ni Benjamen n gbe lati ọdun diẹ sẹyin to ti dero ipinlẹ Ondo.

 

Ileeṣẹ to n fọ epo pupa to wa l’Okitipupa lo si ti n ṣiṣẹ tẹlẹ ki wọn too le e danu lẹyin tọwọ tẹ ẹ pẹlu ọpọlọpọ kẹẹgi epo pupa to ji ko.

Ọpọ ọjọ lo fi wa lakolo awọn ọlọpaa latari iṣẹlẹ ọhun lọdun naa lọhun-un kì wọn too pada tu u silẹ ko maa lọ.

Bo ṣe n jajabọ lọwọ awọn ọlọpaa ni Joseph, ọrẹ rẹ to n gbe l’Akurẹ ranṣẹ si i pe ko tete maa bọ l’Akurẹ ki awọn le jọ maa ṣiṣẹ ole ti oun n ṣe.

Awọn riwaya atawọn to n we kọili ni wọn fara gba ju ninu ọsẹ tawọn ikọ ole ẹlẹni meji yii n ṣe pẹlu bo ṣe jẹ pe aimọye ṣọọbu ni wọn ti ja ti wọn si n ji awọn ẹru bii batiri ọkọ pẹlu awọn kọili ẹnjinni nla eyi ti wọn n we lọwọ.

Ṣọọbu onisọọbu kan ni wọn n ja lọwọ ni idaji ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, tawọn araadugbo kan fi ri wọn. Benjamen nikan lọwọ awọn eeyan ọhun tẹ nigba ti Joseph ọrẹ rẹ wa gbogbo ọna to fi sa mọ wọn lọwọ pẹlu batiri ọkọ mẹfa to ko sa lọ.

Wọn lu Benjamen tọwọ wọn tẹ ni aluki ki wọn too fa a le ọlọpaa lọwọ.

Ogbologboo ọlọsa ọhun ni wọn lo jẹwọ fawọn to mu un pe ọjọ pẹ tawọn ti wa lẹnu iṣẹ batiri ati kọpa waya jiji, o ni ọkunrin Hausa kan ti oun mọ si Yaya ni onibaara kan ṣoṣo to saaba maa n ra awọn ẹru ole naa lọwọ awọn.

Agbegbe Car Street, eyi to wa laarin oju ọna Ọba Adesida si Arakalẹ, niluu Akurẹ, lo ni ọkunrin naa n gbe.

 

Ohun ta a gbọ ni pe awọn ọlọpaa ti n bẹrẹ igbesẹ lori bi ọwọ yoo ṣe tẹ ẹnikeji Benjamen, iyẹn Joseph, ati ẹni tí wọn darukọ gẹgẹ bii onibaara wọn.

 

Leave a Reply