Oloṣelu Eko, Lanre Razak, ti ku o!

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu yii, ni agba oloṣelu ilu Ẹpẹ, nipinlẹ Eko, to ti figba kan ṣe kọmiṣanna fun eto irinna nipinlẹ Eko, Lanre Razak,jade laye lẹni ọdun mẹrinlelaaadọrin(74).

ALAROYE gbọ pe o ti ṣe diẹ ti o ti fẹ si ọkunrin oloṣelu naa, to si ti n gbatọju lọsibitu kan niluu Eko.

Aisan naa lo pada ja siku lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii.

Ọkan ninu awọn oloṣelu pataki to ja fitafita lati di ipo oṣelu kan tabi omi-in mu nipinlẹ Eko ni Razak. O pẹ daadaa ninu ẹgbẹ oṣelu ANPP, ko too dara pọ mọ ẹgbẹ APC, nibi to ti jẹ ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ apaṣẹ to ga ju lọ fun ẹgbẹ naa nipinlẹ Eko..

Leave a Reply