Ọlọpaa ti mu ọkan ninu awọn to ji aburo aṣofin ipinlẹ Ọyọ gbe

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọwọ ọlọpaa ti tẹ ọkan ninu awọn to ji Jumọkẹ Babalọla Oludele, aburo Ọnarebu Sunkanmi Babalọla, ti i ṣe igbakeji awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu to pọ ju lọ nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ gbe.

Jumọkẹ, ẹni ọdun marundinlogoji (35) lawọn agbebọn kan da lọna lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ti wọn si ji i gbe laduugbo Mọnatan, nigboro n’Ibadan, lasiko to n bọ lati ṣọọbu to ti n taja.

Nirọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, lẹyin ti wọn ti daamu jinna, ni wọn too gba ipe abami kan pe akata awọn ajinigbe lẹni ti wọn n wa wa, miliọnu lọna ogun Naira (N20m) lawọn yoo si gba ki awọn too le tu u silẹ nigbekun awọn.

Ṣugbọn laaarọ yii (ọjọ Ẹti Furaidee) lalukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan pe ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ ọkan ninu awọn ajinigbe naa.

Ṣugbọn SP Fadeyi forukọ bo ọkunrin ti wọn mu ọhun laṣiiri lati le jẹ ko rọrun fawọn agbofinro lati ri aburo ọnarebu ti wọn ji gbe gba silẹ laaye, ki wọn si le ri awọn afurasi ọdaran yooku mu.

Leave a Reply