Ọlọdẹ yinbọn paayan l’Ọrẹ, o ni ẹranko loun ri

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ariwo, ‘ẹ dakun ẹ saanu mi, iran mi o paayan ri, ọrọ yii ki i ṣoju lasan, a bi bawo lẹranko ṣe e di eniyan?’ ni baba ọlọdẹ kan, Alagba Isamaila Ojo, fi bọnu lasiko ti wọn n ṣe afihan rẹ ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa loju ọna Igbatoro, l’Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii.

Alagba Ojo ni wọn fi pampẹ ofin gbe lori ẹsun yinyin ibọn pa baba agbalagba ẹni aadọrin ọdun kan nibi to ti n yagbẹ lẹyinkule ile rẹ.

Iṣẹlẹ ọhun ni wọn lo waye ni nnkan bii aago mẹta oru ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, labule kan ti wọn n pe ni Ita-Mẹrin, nitosi Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo.

Nigba to n sọ iha tirẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an, Alagba Ojo ni bii ala niṣẹlẹ naa ṣi n jọ loju oun, nitori pe ẹranko loun ri ti oun yinbọn si loru, bi ẹranko ṣe waa yipada to di eeyan lo ni o si n ṣe oun ni kayeefi.

O ni loju-ẹsẹ ti oun ti ri aṣiṣe oun loun sare pe awọn araadugbo fun iranlọwọ ti awọn si jọ gbe oloogbe ọhun digbdigba lọ si ile-iwosan nibi to pada ku si lẹyin ọjọ diẹ to ti wa nibẹ.

O ni eedi patapata lọrọ ọhun jẹ nitori pe ko si idi kan pato ti oun yoo fi mọ-ọn-mọ pa ẹni ti awọn jọ n gbe laduugbo lai ni idi kan pato.

Alagba Ojo ni ojulowo ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ ọlọdẹ loun, bẹẹ loun ti wa lẹnu iṣẹ ọhun lati ọjọ pipẹ, ti ko si si ninu akọsilẹ ri pe oun ti huwa ọdaran.

 

 

 

Leave a Reply