Ọlọkada fara gbọta lasiko ija awọn aṣọbode ati onifayawọ n’llọrin 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ṣe ni ọrọ di bo o lọ yago lọna, ti onikaluku si n sa asala fun ẹmi rẹ ni opopo Ogidi si Okoolowo, nijọba ibilẹ Guusu Ilọrin (Ilọrin South), Ilọrin, ipinlẹ Kwara, nigba ti ajọ ẹsọ aṣọbode atawọn onifayawọ irẹsi fija pẹẹta, ni nnkan bii aago mọkanla owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ọta ibọn ba ọlọkada kan, to si wa ni ẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun bayii.

Ẹni tọrọ naa ṣoju rẹ to ba ALAROYE sọrọ sọ pe ṣe ni gbogbo agbegbe Ogidi si Okoolowo, daru patapata, ti gbogbo awọn olugbe agbegbe naa ati awọn to n kọja lọ n sa asala fun ẹmi wọn lasiko ti ajọ ẹsọ aṣọbode ati awọn onifayawọ irẹsi bẹrẹ si i yinbọn si ara wọn.

O tẹsiwaju pe awọn ẹsọ asọbode ọhun gba ọkọ kan ti irẹsi kun inu rẹ bamu-bamu lati ẹnu bode ipinlẹ Kwara, wọn si n wa ọkọ naa wọnu igboro Ilọrin pẹlu irẹsi naa, wọn n gbe e lọ si ọfiisi wọn, ṣugbọn nigba ti wọn de agbegbe Ogidi, lawọn to n sowo irẹsi fayawọ lọ rẹbuu awọn ẹsọ asọbode ọhun, ti wọn si bẹrẹ si i ju oko lu wọn, eyi mu ki awọn ẹsọ naa maa yinbọn soke, ṣugbọn nigba ti oko ba ọkan lara awọn ẹṣọ ọhun loju, ti ọwọ ti dun wọn, ni wọn bẹrẹ si i yinbọn leralera, ni awọn onifayawọ naa ba bẹrẹ si i yinbọn, ni gbogbo agbegbe yii ba daru.

O ni awọn ẹsọ aṣọbode pada sa lọ, ti wọn si gbe ọkọ irẹsi naa kalẹ, ti awọn onifayawọ si pada gbe ọkọ wọn lọ pẹlu irẹsi to wa ninu rẹ, ṣugbọn lasiko ti ija n gbona lọwọ ni ọta ibọn ba ọlọkada kan, ti wọn si ti  gbe e lọ sileewosan fun itọju to peye.

 

Leave a Reply