Ọlọkada kan ku l’Oṣogbo, bireeki ọkada rẹ lo ja lojiji

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin ọlọkada kan la gbọ pe o ti padanu ẹmi rẹ laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lasiko ti bireeki ọkada rẹ ja lori ere.

Ere asapajude ti ọlọkada naa ba de orita Lameco, loju-ọna Oṣogbo si Ikirun, la gbọ pe o mu ki ijamba naa lagbara pupọ nigba ti bireeki rẹ ja lojiji.

Alukoro ajọ ẹṣọ oju popo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, ṣalaye pe aago meje aarọ ku iṣẹju mẹwaa laaarọ Mọnde niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

O ni ọkada Boxer Bajaj pupa ni ọmọkunrin ti wọn ko ti i mọ orukọ rẹ ọhun wa, oun nikan lo si wa lori rẹ.

Ogungbemi ṣalaye pe wọn ti gbe oku ọkunrin ọlọkada naa lọ sile igbokuu-pamọ-si ti ileewosan UNIOSUN Teaching Hospital, nigba ti wọn gbe ọkada ati foonu rẹ lọ si ọfiisi awọn ajọ ẹṣọ oju popo.

Leave a Reply