Ọlọkada ko sẹnu tirela l’Arigbajo, oun atero lo ku

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun, lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni ọlọkada kan atero to gbe sẹyin pade iku ojiji loju ọna Eko si Abẹokuta, nibudokọ  Oni & Sons, l’Arigbajo.

Ko sohun to fa a ju pe ọlọkada naa fi aibikita ko sabẹ tirela lọ.

 

 

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ẹni to wa ọkada naa ko fara balẹ, ko si jọ pe o kọbi ara si oju popo to wa rara.

Wọn ni ọlọkada ti nọmba ẹ jẹ TRE 301 VW naa lo lọọ ko sẹnu tirela, to fi di pe iyẹn tẹ ẹ pa pẹlu ero to gbe sẹyin.

Babatunde Akinbiyi ti i ṣe Alukoro TRACE, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ.

 

 

O ni  KNN 357 ZY ni nọmba tirela to tẹ wọn pa. O fi kun un pe awọn ọmọọta tiẹ fẹẹ dana sun tirela ọhun, bi ko ba jẹ pe awọn tete kapa wọn ni.

Mọṣuari ọsibitu Jẹnẹra Ifọ ni wọn gbe awọn oku mejeeji naa lọ bi Akinbiyi ṣe wi.

Leave a Reply