Ọlọkada ku si titi l’Abiọla Way, l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ko sẹni to mọ orukọ ẹ tabi ibi to ti n bọ, iyẹn ọkunrin ọlọkada kan ti wọn deede ri oku ẹ loju ọna Abiọla Way, l’Abẹokuta, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii.

Gbalaja lọkunrin naa na kalẹ pẹlu ọkada ẹ to paaki sẹgbẹẹ kan, bẹẹ ni ifoofo ṣi n yọ lẹnu ẹ lasiko ti a n kọ iroyin yii lọwọ.

Ṣaaju ni Gomina Dapọ Abiọdun ti paṣẹ pe kawọn ọlọkada ma ṣiṣẹ lonii, nitori bo ṣe jẹ pe ọkada lawọn to n fa wahala n gun kiri ti wọn fi n ṣiṣẹ ibi. Ṣugbọn ko jọ pe awọn eeyan naa gbọrọ sijọba lẹnu rara, nitori kaakiri igboro Abẹokuta lawọn kan ninu wọn ti ṣiṣẹ. Koda wọn ni wọn ṣiṣẹ n’Ilaro naa.

Àwọn kan tilẹ ba ara wọn ja l’Ọbantoko, ti wọn gun ara wọn nigo, ṣugbọn ko sẹni to ti i mọ ohun to fa iku eyi ti wọn ri oku ẹ ni titi yii, bẹẹ ni ko sẹni to mọ ibi to ti n bọ tabi ibi to n lọ.

Leave a Reply