Ọkada Honda kan to ni nọmba GBE 476 WU, n sare loju ọna marosẹ Eko si Abẹokuta lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa yii, o sare ya ọkọ ayọkẹlẹ kan silẹ, nigba naa lo sẹri mọ tirela to n lọ loju ọna tiẹ. Ọlọkada yii kan lapa, ṣugbọn ọlọmọge to gbe sẹyin bii ero ku lẹsẹkẹsẹ ni.
Gẹgẹ bawọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe wi, wọn ni Iyana Sẹlẹ ni wọn n pe agbegbe ti ijamba yii ti waye, iyana kan wa nibẹ nitori atunṣe to n lọ lọwọ loju ọna Sango Ọta.
Wọn ni Sango ni ọlọkada naa n lọ, ṣugbọn niṣe lo lọọ kọ lu tirela to n lọ s’Abẹokuta, eyi ti nọmba rẹ jẹ KRD 43 XE.
Ikọlu naa lagbara pupọ bi wọn ṣe wi, to bẹẹ to jẹ niṣe ni apa kan ọlọkada naa run womuwomu, ti ero to gbe sẹyin ko si ye, to jẹ ọmọbinrin naa ku lẹsẹkẹsẹ ni.
Dẹrẹba to wa tirela sa lọ pẹlu ọmọ ẹyin ọkọ ti wọn jọ wa nibẹ, awọn TRACE lo si gbe ọlọkada to kan lapa lọ sile iwosan jẹnẹra Ifọ, ti awọn ẹbi ọmọ to doloogbe si gba oku ẹ, ti wọn lọọ sin in.