Ọlọpaa ṣafihan awọn janduku tọwọ tẹ lasiko iwọde SARS l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ 

Awọn afurasi janduku bii mejidinlogun nileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ṣafihan ni olu ileesẹ wọn to wa loju ọna Igbatoro l’Akurẹ, lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii.

Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, ṣalaye fawọn oniroyin pe gbogbo awọn afurasi ọhun atawọn mi-in ti awọn ṣi n wa ni wọn lọwọ ninu ọkan-o-jọkan iwa ọdaran to waye lasiko ti iwọde naa fi n lọ lọwọ.

Mẹta ninu wọn lo ni awọn ri mu si i niluu Ọwọ, ọwọ tẹ mẹrin ninu awọn to dana sun olu ile ẹgbẹ APC l’Akurẹ, awọn meji l’Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo, wọn mu awọn afurasi mẹfa to lọwọ ninu didana sun tesan awọn SARS to wa wa loju ọna Ọda, pẹlu awọn mẹta tawọn sọja mu.

Salami ni loootọ ni inu awọn dun pupọ fun bi ọwọ ṣe tẹ awọn adaluru naa lasiko, o ni ọkan awọn ko ti i balẹ rara lori ọrọ ìbọn awọn meji to ṣi wa ni ikawọ awọn ọdaran ọhun.

O fi kun un pe iwadii ti pari patapata lori ẹsun ti wọn fi kan gbogbo awọn tọwọ tẹ ọhun, ati pe ko ni i pẹ rara ti wọn yoo fi foju bale-ẹjọ lati lọọ sọ tẹnu wọn.

Leave a Reply