Ọlawale Ajao, Ibadan
Awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii, ti wọn si ti n fimu finlẹ lati ṣawari aọn eeyan kan ti wọn ṣe idajọ lọwọ ara wọn pẹlu bi ọn ṣe dana sun awọn ole meji kan to ji ọkada gbe niluu Ibadan lọsẹ to kọja yii.
Kirakita awọn adigunjale meji naa pin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ogunjọ, oṣu Keje, ọdun 2022 yii, pẹlu bi awọn eeyan ṣe dana sun wọn lẹyin ti wọn ji ọkada gba lọwọ awọn ọlọkada n’Ibadan.
Laduugbo General Gas, n’Ibadan, lọna Akobọ, ni wọn ti ji ọkada gbe, wọn ko ti i ri alupupu ọhun gbe sa lọ tọwọ fi ba wọn, labẹ biriiji to wa laduugbo naa ni wọn si dana sun wọn si.
ALAROYE gbọ pe ni kete tọwọ ti ba awọn adigunjale ti a ko morukọ wọn yii lawọn kan laduugbo ọhun ti tẹ awọn agbofinro laago, ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa yoo fi de, awọn adigunjale naa ti gba inu ina aye dọrun apaadi.
Tẹ o ba gbagbe, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, lawọn eeyan dana sun awọn meji kan naa ti wọn fẹẹ fipa gba ọkada lọwọ ọlọkada, adugbo Ologun-Ẹru, n’Ibadan, ni wọn ti jale, ọna Sango si Ijoko, n’Ibadan, ni wọn ti dana sun wọn.
Eyi to buru ju ni iṣẹlẹ eyi ni pe awọn eeyan naa ko ti i jona tan ti awọn to to fẹẹ ra ẹya ara ati ẹran eeyan ti de. Ni gbangba titi nibẹ naa lawọn kan si ti bẹrẹ si i fi ọbẹ ge ẹran awọn eeyan yii ta bii ẹni ta ẹran maaluu lọja.
Bi wọn ṣe dana sun wọn tan lawọn kan ti yọ ada ati ọbẹ ti oku wọn, ti wọn bẹrẹ si i ge ẹya ara wọn ta lọkọọkan. Wọn si ge ẹran eeyan silẹ bayii, awọn eeyan si n sanwo, wọn si n ra a. Ẹni ti ko ta tiẹ si n gbe e lọ.
Awọn ọmọ Yahoo la gbọ pe wọn ra ẹran ati ẹya ara awọn adigunjale ti awọn ọlọkada dana sun naa.