Ọlọpaa ṣawari awọn ọmọde mẹwaa ti wọn loyun ni Mowe, obinrin kan lo n ta awọn ọmọ ti wọn ba bi

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ile kan wa lagbegbe Ọfada si Mowe, ni ipinlẹ Ogun, awọn ọmọbinrin tọjọ ori wọn ko ju mejidinlogun si mẹrinlelogun lọ ni wọn n ṣabiyamọ nibẹ, ti iya kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Florence Ogbonna si n ta awọn ọmọ ti wọn ba bi, to n fowo ẹ ṣararindin.

Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun lo jẹ ki aṣiri ohun ti wọn n ṣe ninu ile naa tu lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kin-in-ni, oṣu kejila, ọdun yii.  Wọn ya bo ile naa lẹyin ti olobo ta wọn, nibẹ ni wọn si ti ko awọn ọmọdebinrin mẹwaa ti wọn ṣe ikun kinrindin pẹlu oyun jade.

Ohun to ṣẹlẹ gẹgẹ bi CP Abimbọla Oyeyẹmi to fi iṣẹlẹ naa sita ṣe wi ni pe iya ti wọn n pe ni Florence Ogbonna yii maa n lọọ ko awọn ọmọdebinrin ọlọmọge wa lati awọn ipinlẹ bii, Imo, Abia ati Ebonyi. Yoo sọ fawọn obi wọn labule pe iṣẹ wa l’Ekoo toun yoo fi wọn si, ko si ni i pẹ tawọn ọmọ naa yoo fi maa fowo ranṣẹ si wọn. N lawọn obi yoo ba yọnda awọn ọmọ wọn fun un.

Ṣugbọn nigba to ba ko wọn de ile rẹ ni Mowe tan, ọkunrin alaabọ ara kan to mọ bi wọn ṣe n ba obinrin sun daadaa ni yoo maa ba awọn ọmọdebinrin naa sun, wọn ko ni i ṣiṣẹ kan ju ibalopọ lọ.

Oyun ni yoo gbẹyin ibasun, ọmọ ni wọn yoo fi bi gẹgẹ bi alukoro ṣe wi. Ṣugbọn ki i ṣe pe wọn yoo maa tọju ọmọ naa, iya ti wọn n pe ni Florence Ogbonna yii ni yoo ta ọmọ naa fawọn onibaara rẹ to maa n ta wọn fun, yoo gbowo rẹ sapo, yoo si maa ṣe faaji tiẹ lọ.

Ọkan ninu awọn ọmọ to ko de lati abule lo bimọ laipẹ yii, Chidera Onuoha lorukọ ọmọge to bimọ naa. Ọmọ to bi ni Florence fẹẹ ta bii iṣe rẹ, niyẹn ba yari pe oun ko le jiya oyun, koun ranju bimọ, kẹnikan waa fẹẹ gba ọmọ naa lọwọ oun, bo ṣe lọọ sọ ohun to n ṣẹlẹ nile Florence fọlọpaa niyẹn.

Lori iye ti iya yii n ta awọn ọmọ ikoko naa, Chidera sọ pe to ba jẹ ọmọkunrin ni, ẹgbẹrun lọna igba ataabọ (250,000) ni. To ba jẹ obinrin, ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000) niyẹn.

Ṣugbọn nigba tawọn ọlọpaa de lati mu Florence atawọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ to lodi sofin yii, iya naa sa lọ mọ wọn lọwọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ri ọkunrin alaabọ ara to n fun wọn loyun mu, bẹẹ ni wọn mu ọmọ Florence kan toun naa jẹ obinrin.

Yatọ sawọn oloyun mẹwaa ti wọn ba ninu ile yii, awọn ọmọde kan naa wa nibẹ tawọn ọlọpaa tun ko mọ wọn.

Wọn ti fi awọn tọwọ ba si ahaamọ, ijẹjọ wọn yoo bẹrẹ laipẹ, bẹẹ ni Florence Ogbonna naa yoo jẹjọ lilo ọmọ nilokulo ati fifi ọmọ ikoko ṣe owo.

Leave a Reply