Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Titi dasiko ta a pari iroyin yii ni wọn ṣi n wa awọn ọmọde marun-un to deede dawati nile awọn ọmọ alainiyaa ti Stella Ọbasanjọ to wa n’Ibara, l’Abẹokuta.
Kọmiṣanna eto iroyin nipinlẹ Ogun, Alaaji Waheed Oduṣile, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii. Oduṣile ṣalaye pe Ọjọbọ ọsẹ to kọja lawọn ọmọde naa jade kuro ninu ọgba ile wọn ti wọn n gbe, bi eyi si ṣe de setigbọọ ijọba ipinlẹ Ogun lawọn ti fi to awọn ọlopaa leti, tawọn si ti bẹrẹ igbesẹ lati wadii awọn to n ṣiṣẹ ninu ọgba ile ọmọ alainiyaa naa.
‘Gbogbo ẹka tọrọ yii kan la ti fi to leti, bẹẹ ni gbogbo awọn to wa lẹnu iṣẹ lasiko tawọn ọmọ naa jade sita nijọba ti fọrọ wa lẹnu wo. Ṣugbọn a fẹ kawọn ọlọpaa maa ba iwadii wọn lọ na ka too tẹsiwaju ninu igbesẹ tiwa’’ Oduṣile lo sọ bẹẹ lorukọ ijọba ipinlẹ Ogun.
O fi kun un pe ipinlẹ Ogun ki i ṣe ibi tawọn oniṣẹ ibi le mule si, o ni bi iwadii ba fidi ẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ ile awọn ọmọ alainiyaa naa lọwọ ninu ohun to ṣẹlẹ yii, gbogbo wọn ni wọn yoo koju ofin gẹgẹ bo ṣe to.
Ko si aaye ijade tabi irinkurin nile awọn ọmọ Stella Ọbasanjọ gẹgẹ bi Oduṣile ṣe sọ, bi wọn ṣe dawati yii lọwọ ninu, o si jẹ nnkan iyanu.
Inu Ibara Housing Estate, l’Abẹokuta, ni ile awọn ọmọ alainiyaa yii wa, geeti wa lẹnu ọna abawọle, ki i ṣe ibi gbayawu rara.
Lẹyin iku iyawo Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, Ọmọwe Stella Ọbasanjọ, ni wọn sọ ile naa lorukọ obinrin yii lati maa fi ṣeranti rẹ.