Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori afurasi ajinigbe ti wọn pa l’Omuo-Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti to bẹrẹ iwadii lori ọrọ afurasi ajinigbe tawọn eeyan lu pa niluu Omuo-Ekiti, ti i ṣe olu-ilu ijọba ibilẹ Ila-Oorun Ekiti.

Lopin ọsẹ to kọja niṣẹlẹ naa waye ni Iludọfin, pẹlu bi wọn ṣe ni ọkunrin ti ọjọ ori ẹ ko ti i ju ogoji ọdun lọ naa gbiyanju lati ji ọmọ ọdun meje kan gbe, ṣugbọn tawọn eeyan mu un, ti wọn si lu u pa.

Ẹnikan to mọ nipa iṣẹlẹ ọhun sọ fun wa pe ileewe lọmọdekunrin naa ti n bọ pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ ni nnkan bii aago meji ọsan ti onikaluku si n ya sọna ile ẹ, ṣugbọn wọn ko mọ pe ajinigbe kan n tẹle wọn.

Bi ọkan ninu wọn ṣe kuro laarin awọn to ku, to si n gba ọna kan to da diẹ lọ sile ni afurasi naa tẹle e, bo si ṣe ki i mọlẹ lo wọ ọ wọ inu igbo, ṣugbọn ẹnikan ri i nigba to ṣe bẹẹ.

Ariwo la gbọ pe ẹni to ri i pa, awọn eeyan si ya jade lati mu afurasi ajinigbe naa, bẹẹ ni wọn lu u titi to fi daku.

Nigba to ya lawọn ọlọpaa de, ti wọn gba a silẹ lọwọ ọgọọrọ eeyan to n lu u, ṣugbọn bi wọn ṣe gbe e de teṣan lo dagbere faye.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, ASP Sunday Abutu, ṣalaye pe oloye Iludọfin kan lo fọrọ naa to awọn ọlọpaa leti ti wọn fi lọ sibẹ, o si gba wọn lasiko diẹ ki wọn too ri afurasi naa gba lọwọ awọn araalu. O ni wọn sare gbe e lọ si teṣan lati daabo bo o, ṣugbọn bi wọn ṣe ni kawọn gbe e lọ sileewosan lo dakẹ.

Abutu waa bẹnu atẹ lu iwa kawọn eeyan maa ṣedajọ fun afurasi, o ni ki wọn maa fa ẹni ti wọn ba mu pe o huwa ọdaran lọ teṣan nikan ni igbesẹ to tọna.

Leave a Reply