Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori akẹkọọ ati olukọ tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun pa l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti ni iwadii tawọn n ṣe lọwọ lori iṣẹlẹ bi wọn ṣe yinbọn pa akẹkọọ ileewe Micheal Ọtẹdọla College of Primary Health Education (MOCPEC), to wa nijọba ibilẹ Ẹpẹ, Ọgbẹni Rasak Bakare, ati olukọ ileewe ọhun, Ọgbẹni Saheed Ahmed, ti fihan pe iṣẹlẹ naa ko ṣẹyin awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun.

Ba a ṣe gbọ, inu ṣọọṣi kan to wa niluu Nọforija, ni Bakare sare jannajanna wọ lati sa asala fẹmi-in rẹ  nigba tawọn ti wọn fẹẹ pa a n le e, Inu ṣọọṣi naa ni wọn ka a mọ, ti wọn si yinbọn pa a nibẹ lọjọ Wẹsidee to kọja.

Ọjọ kẹta lẹyin ẹ, lọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn lọọ ka olukọ MOCPEC kan, Ọgbẹni Saheed, mọ ile rẹ niluu Pọka, lagbegbe Ẹpẹ, nipinlẹ Eko, ti wọn si fibọn gbẹmi oun naa.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, sọ lọjọ Aiku, Sannde yii, pe iṣẹlẹ ti akẹkọọ ti wọn pa sinu ṣọọṣi lawọn gbọ nipa ẹ, awọn ọtẹlẹmuyẹ si ti n ṣiṣẹ le e lori, o lawọn o gbọ nipa ti olukọ (lecturer) ti wọn pa lọjọ Furaidee yii.

O ni bo tilẹ jẹ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju, awọn ẹri ti fihan pe awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun lo wa nidii iṣẹlẹ naa, pe wọn n fẹmi di ẹmi ni, wọn gbẹsan lara ara wọn.

Iṣẹlẹ yii la gbọ pe o da jinnijinni bo awọn olugbe agbegbe Ẹpẹ, ti Aladesoyin, tilu Odo-Noforija, Ọba Babatunde Ogunlaja atawọn aṣofin to n ṣoju agbegbe Ẹpẹ ti n fori kori lati dẹkun iwa laabi awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ọhun.

Bakan naa ni Alara ti ilu Ilara, Ọba Olufọlarin Ogunsanwo, fidi iṣẹlẹ ti tiṣa ti wọn pa naa mulẹ, o si rọ awọn agbofinro lati fiya jẹ awọn to huwa laabi ọhun.

Leave a Reply

%d bloggers like this: