Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori Ẹbunoluwa ti wọn pa sinu ile awọn obi rẹ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwadii lori iku ọmọbinrin ẹni ogun ọdun kan, Ẹbunoluwa Ọsatuyi, ẹni ti wọn pa sinu ile awọn obi rẹ to wa lagbegbe Okuta Ẹlẹrinla, niluu Akurẹ.

Ẹbunoluwa to n mura ati wọ ile-ẹkọ giga laipẹ yii la gbọ pe wọn pa lọsan-an ọjọ naa lẹyin to pada sile lati ibi to ti n n gba idanilẹkọọ ni igbaradi fun idanwo JAMB to n bọ lọna.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ọdọ araadugbo kan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ pe oju ferese ile lawọn oniṣẹẹbi naa gba wọle. O ni oju ọgbẹ nla tawọn eeyan ri lori ọmọbinrin naa fihan pe ṣe ni wọn la nnkan mọ ọn lori, leyii to ṣokunfa iku rẹ. Bakan naa lo ni wọn ṣi ba ọmọ odo ati aake eyi ti wọn lo lati fi ran ọmọbinrin naa sọrun ọsan gangan ninu yara ibi ti wọn pa a si.

Ninu alaye ti iya Oloogbe, Abilekọ Bọsẹde Ọsatuyi, ṣe fawọn oniroyin, o ni kayefi gidigidi lo jẹ foun lati ba ọmọ oun ninu agbara ẹjẹ nigba toun pada de lati ibi isẹ ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ iṣẹlẹ naa.

O ni oun ati ọkọ oun lawọn jọ ri i nibi ti wọn de e lokun si ni palọ awọn, ti ẹjẹ si n ṣan jade lati ibi oju ọgbẹ to wa lori rẹ.

Kiakia lo ni awọn ti sare gbe e digbadigba lọ si ileewosan kan boya awọn ṣi le ri ẹmi rẹ du, ṣugbọn awọn dokita sọ pe o ti ku.

Abilekọ Ọsatuyi waa bẹ ijọba ipinlẹ Ondo atawọn ẹṣọ alaabo lati ṣawari awọn to ṣeku pa ọmọ oun lọnakọna, ki wọn le foju wina ofin.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmi Ọdunlami, ni awọn ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori ọrọ iku ọmọbinrin naa.

 

 

 

Leave a Reply