Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori ọkunrin to n fi ọkada jiṣẹ kiri to ti ọmọ mọnu apoti to fi n ko nnkan l’Ekoo

Faith Adebọla

Igbaju igbamu ni wọn fi da ọkunrin kan to n fi jiṣẹ kiri niluu Eko lọla, laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹta yii, bi ko ba si si tawọn agbalagba to tete da sọrọ naa ti wọn fi ni ki wọn wọ ọ lọ sagọọ ọlọpaa ni, boya niṣe ni wọn iba lu u pa, latari bi wọn ṣe ni wọn ba ọmọ kekere kan ninu apoti to n ko nnkan si, eyi to gbe sẹyin ọkada rẹ, ọmọọlọmọ kan lọmọ ọhun.

Ba a ṣe gbọ, adugbo kan ti wọn n pe ni Ṣangotẹdo, lagbegbe Lẹkki, nijọba ibilẹ Eti-Ọsa, ipinlẹ Eko, niṣẹlẹ yii ti waye.

Ninu fidio kan to n ja ranyin ni ikanni tuita (twitter) lori ẹrọ ayelujara, a ri i bawọn eeyan ṣe n din dundu iya loriṣiiriṣii fun afurasi ọdaran tẹnikan o ti i mọ orukọ rẹ, ti wọn loun lo gun ọkada alawọ buluu naa debẹ, a ri ọkada ọhun, bẹẹ lẹnikan gbe ọmọ-ọwọ naa dani, wọn n gbe e tẹle ọkunrin yii, wọn si lu u bi wọn ṣe n wọ ọ lọ si teṣan ọlọpaa.

Ẹnikan sọrọ ninu fidio ọhun pe “ọmọ ti wọn ri nibẹ niyẹn, inu apoti to wa lẹyin ọkada ẹ ni wọn ti r’ọmọ. Gbọmọgbọmọ lọkunrin yii, ẹ mu un daadaa, o maa jẹwọ, Hausa ni.”

Ẹlomi-in tun sọ ninu fidio naa pe: “Afi k’Ọlọrun gba wa o, ko si lẹta rara ninu apoti to n gbe kiri, ọmọ lo ji pamọ sibẹ, awọn oloriburuku gbogbo.”

AKEDE AGBAYE pe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko lori foonu ẹ lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, CSP Adekunle Ajiṣebutu sọ pe awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, ṣugbọn awọn ṣi n ṣewadii lati mọ ẹni to wa ninu fidio ọhun ni.

O lẹnikan o ti i mẹjọ wa si teṣan ọlọpaa lori iṣẹlẹ yii, ṣugbọn Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Abiọdun Alabi, ti da awọn ọmọọṣẹ rẹ sita lati tọpinpin iṣẹlẹ ọhun.

Leave a Reply