Ọlọpaa gbe Igbakeji olori ile-igbimọ aṣofin Ogun ju satimọle

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, ahamọ awọn ọlọpaa ni Igbakeji olori ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun, Ọnarebu Oludare Kadiri, wa, l’Eleweeran, l’Abẹokuta.

Ohun to fa eyi ko ṣẹyin bi wọn ṣe ni ọkunrin naa ko awọn janduku lẹyin lati kọ lu ile Akọwe ijọba Gomina Dapọ Abiọdun, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi, ni Oru-Ijẹbu, nijọba ibilẹ Ariwa Ijẹbu, lọsẹ to kọja, lasiko iforukọsilẹ ẹgbẹ APC. Wọn lo tun kọ lu ile Abilekọ Toun Oduwọle ati ẹnikan to n jẹ Adekunle Yinusa.

ALAROYE gbọ pe nitori nnkan eelo iforukọsilẹ ẹgbẹ oṣelu APC ni Kadiri tawọn eeyan tun n pe ni Maba, tori ẹ ko ran awọn janduku lọ sile sawọn ile yii, ti wọn si ko wọn ni papamọra, ti wọn ba ilẹkun atawọn ferese ile naa jẹ.

Lati fidi ọrọ yii mulẹ, ALAROYE pe Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi. Ọlọpaa naa sọ pe loootọ lawọn ti mu Igbakeji awọn aṣofin Ogun ju sẹka itọpinpin, awọn ti bẹrẹ iwadii lori rẹ, awọn yoo si gbe e lọ si kootu bi ọrọ rẹ ba jọ mọ ile-ẹjọ.

Oyeyẹmi ṣalaye pe eeyan meji lo waa fẹjọ rẹ sun ni teṣan pe o ran awọn eeyan lọ sawọn ibi kan lati ba ibẹ jẹ.

O ni kansilọ kan to n bojuto awọn nnkan eelo iforukọsilẹ naa sọ fawọn ọlọpaa pe awọn ọmọ ẹyin Kadiri fipa ko awọn eelo naa nibi ti awọn ko wọn si, awọn ọlọpaa si lọ sibẹ lati ko awọn nnkan naa.

O ni nigba ti kansilọ yẹn n pada bọ, janduku bii ogun ni Kadiri ko lẹyin lati kọ lu u, niṣoju awọn ọlọpaa lo si ti bẹrẹ si i ba ọkunrin naa ja.

Oyeyẹmi sọ pe o gba awọn ọlọpaa lasiko diẹ ki wọn too ri ọkunrin naa gba lọwọ Kadiri, idi niyẹn tawọn fi mu un.

Ṣugbọn Kadiri ti wọn n fẹsun kan ni ko sohun to jọ bẹẹ, o ni Akọwe ijọba gomina ko wulẹ fẹran oun latilẹ ni, ati pe latigba ti Gomina Abiọdun ti yan an sipo lawọn ko ti rẹ lori ọrọ oṣelu Ariwa Ijẹbu.

O fi kun un pe miliọnu mẹwaa naira ti Gomina Dapọ Abiọdun gbe fun Talabi lasiko Keresimesi to kọja pe ko pin in fawọn ijọba ibilẹ, toun si n da a laamu pe ko lọọ pin in fun wọn lo tori ẹ ba oun wa ọran ti wọn fi mu oun yii.

‘’Emi kọ ni mo ran ẹnikẹni lati lọọ kọ lu ile akọwe ijọba gomina. Iwadii mi fi han pe awọn to kọ lu ile rẹ n wa ounjẹ Korona ti wọn lo ko pamọ sile ni, wọn fẹẹ ko o, nitori o ṣi pin ounjẹ fawọn eeyan ẹ ninu oṣu kejila, ọdun to kọja.

 

‘’Talabi kan n sọ mi lorukọ buruku lati ko ba mi nitori oṣelu ni’’

 

Igbakeji aṣofin yii loun lọọ forukọ silẹ ni wọọdu oun ti i ṣe Aba paanu ni, wọọdu kọkanla, o ni boun ṣe ṣetan nibẹ loun pada sile oun.

O ni nibi toun ti n ṣe faaji pẹlu awon eeyan oun lọwọ l’Agọ-Iwoye ni Ọnarebu Ọbagun ti waa ba oun pe awọn ọlọpaa ti yi ile oun po( Ile Ọbagun).

‘’Mo ni ki Ọbagun pe iyawo ẹ pe ko ma jẹ ki wọn wọle bi ko ba ti ri i pe ọlọpaa ni wọn. Iyawo Ọbagun pe lori foonu pada pe wọn ti ja ilẹkun wọle. Emi ati Ọbagun jọ de ile rẹ, a ba DPO nibẹ, mo beere pe kin ni wọn n wa, wọn ni awọn nnkan iforukọ silẹ ni, ibẹ la wa ti wọn ti waa sọ fun wa pe awọn kan tun ti kọ lu ile Talabi, mo dẹ lọ sibẹ lati pẹtu si wọn lọkan, emi gan-an ni mi o jẹ kawọn janduku yẹn wọle’’

Ṣa, Ọnarebu Oludare Kadiri ṣi wa ni gbaga l’Eleweeran, o le jẹ kootu ni yoo yanju ọrọ naa gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ṣe wi.

Leave a Reply