Ọlọpaa kan ọlọkada lẹsẹ, lawọn araalu ba lu u lalubami l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Alubami lawọn eeyan agbegbe Owo-Ẹba, loju-ọna Garaaji Ileṣa, lu ọlọpaa kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, latari bo ṣe kan baba agba kan, Ọgbẹni Hamzat Kazeem, lẹsẹ.

Baba yii la gbọ pe ọmọ rẹ gbe si ori ọkada, ti wọn si n lọ si ọdọ ajorin kan lagbegbe naa, ṣugbọn ti awọn ọlọpaa ro pe ṣe ni wọn fẹẹ sa fun awọn.

Bi ọlọpaa kan ṣe pakuuruku mọ wọn pẹlu ibọn lo n lọ ọwọ ọkada mọ ẹni to wa a lọwọ, bi awọn mejeeji ti wọn wa lori ọkada ṣe ṣubu sinu koto niyẹn, ti baba si kan lẹsẹ.

Eleyii lo bi awọn ọdọ tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ninu, wọn ṣina iya fun ọlọpaa to ṣiṣẹ naa, wọn si lu u bii kiku bii yiye ko too di pe awọn ẹgbẹ rẹ pẹlu awọn Amọtẹkun de sibẹ.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa ni ọsibitu ti wọn ti n ba a to eegun to kan ninu ẹsẹ rẹ, Ọgbẹni Hamzat ṣalaye pe agbẹ loun, bẹẹ loun si n ta pako (planks).

O ni, “Mo n lọ soko laaarọ yii ni, ọmọ mi lo si fi ọkada gbe mi. O ku diẹ ka de Owo-Ẹba ni mo ni ko ya ọdọ ajorin kan ti mo fẹẹ ri nibẹ, bẹẹ awọn ọlọpaa wa lọọọkan.

“Ṣe ni awọn agbofinro yii ro pe a fẹẹ sa lọ, bi a ṣe ya sọna ọdọ ajorin bayii ni ọkan lara wọn n bọ lọdọ wa, to si na ibọn si wa. Ẹru ti ba ọmọ mi, sibẹ ọlọpaa yẹn ko dawọ duro.

“Lo ba bẹrẹ si i lọ ọwọ ọkada mọ ọmọ mi lọwọ, bi ọkada ṣe fẹgbẹ lelẹ niyẹn, emi ati ọmọ mi ṣubu.

“N ko le da dide mọ tori ẹsẹ yẹn ti kan, bẹẹ ni mo so ọlọpaa yẹn laṣọ mu, n ko jẹ ko sa lọ, o bẹrẹ si i bẹ mi pe ki n jẹ ki oun lọ ati pe oun yoo sanwo itọju mi.

“Awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ wa loju-ọna ni wọn gbe mi wa sibi, bẹẹ ni awọn ọlọpaa mi-in tun ti wa wo mi”

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Alakooso awọn Amọtẹkun l’Ọṣun, Amitolu Shittu, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni bi awọn ṣe gbọ ni ikọ Amọtẹkun ti kọja sibẹ lati le pese aabo fun ẹmi ati dukia awọn araalu.

Leave a Reply