Ọlọpaa ko olóṣó ọgọrun-un, wọn ni wọn fẹẹ baye jẹ lojumọmọ

Ko din ni ọgọrun-un kan awọn oloṣo to bọ sọwọ ọlọpaa l’Ọjọbọ, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ yii, nibi ti wọn ti n ṣowo nabi lojumọmọ nibudo okoowo awọn ọlọja mi-in ni Nairobi, lorilẹ-ede Kenya.

Gẹgẹ bi ẹka iroyin ‘The Standard’ ṣe ro o, wọn ni awọn ọlọja ti wọn wa ni gbangba ibudo okoowo ti wọn n pe ni CBD, ni Nairobi ni wọn kọwe sijọba pe awọn ko ni i sanwo ori mọ o, to ba ti jẹ ijọba ko ni i waa ko awọn aṣẹwo ti wọn n fojumọmọ ṣeṣekuṣe niwaju ṣọọbu awọn.

Awọn ọlọja naa sọ pe aago meje aarọ lawọn aṣẹwo naa yoo ti le ara wọn siwaju ṣọọbu awọn, abi lẹgbẹẹ-gbẹ awọn ṣọọbu naa, ti wọn yoo maa pe awọn ọkunrin to n lọ pe ki wọn waa ba awọn dowo nabi pọ, ti awọn ti oju ki i ti ninu awọn ọkunrin naa yoo si maa da wọn lohun.

Wọn fi kun un pe ofin tijọba ṣe, pe eeyan ko gbọdọ jade mọ lẹyin aago mẹwaa alẹ ni Kenya nitori ofin Korona lo mu kawọn aṣẹwo yii bẹrẹ iṣẹ lojumọmọ, to bẹẹ to jẹ bawọn to fẹẹ ra ọja gidi ba ti ri awọn oloṣo yii, niṣe ni wọn yoo gbagbe ohun ti wọn fẹẹ ra, ti wọn yoo ba oloṣo lọ lojumọmọ.

Bi eyi ba wa n lọ bẹẹ, tijọba ko tete waa palẹ awọn oloṣo yii mọ, awọn ọlọja lawọn o ni i sanwo ori mọ o.

Yatọ sawọn ọlọja, awọn ileewe kan naa tun kọwe sijọba, wọn ni niwaju ileewe lawọn aṣẹwo yii tun n duro, to jẹ amuku siga atawọn nnkan radarada ti wọn lo silẹ yoo kun iwaju ileewe ni. Gbogbo ifisun yii lo mu kawọn ọlọpaa bẹrẹ si i dọdẹ awọn aṣẹwo yii, awọn ti wọn ni Duruma Roodu ni wọn ti n ṣiṣẹ wọn, atawọn ti wọn ni wọn n duro niwaju ileewe Central Day Nursery School, ni Ngariama Roodu.

Bii ẹni mu adiẹ ju sinu ago lọwọ si ṣe ba wọn l’Ọjọbọ naa, wọn ko din lọgọrun-un kan ti yoo foju wina ofin ijọba.

Leave a Reply