Ọlọpaa lawọn yoo wadii were ti wọn ba ibọ lọwọ rẹ tawọn kan dana sun l’Abule Ado

Faith Adebọla, Eko

Ileeṣẹ ọlọpaa Eko lawọn ti bẹrẹ iwadii lori bi awọn janduku kan ṣe mu obinrin kan ti wọn lo larun ọpọlọ, ti wọn de e lokun, ti wọn si dana sun un, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe wọn ba ọmọde jojolo kan ninu baagi ẹ pẹlu ibọn oyinbo AK-47 mẹta.

Irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde yii, la gbọ pe iṣẹlẹ yii waye ni adugbo ti wọn n pe ni Abule Ado, labẹ biriiji to wa lagbegbe Festac, l’Ekoo.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi, fi ṣọwọ s’ALAROYE, Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, Hakeem Odumosu, ni iwadii ranpẹ kan tawọn ṣe nipa iṣẹlẹ naa fihan pe obinrin ti wọn dana sun ọhun ti n gbe lagbegbe naa fun ọpọ ọdun, wọn ni inu ile akọku kan lo n sun si lalaalẹ, ṣugbọn ori akitan kan lo saaba maa n wa lojumọmọ.

Wọn lawọn janduku kan ni wọn ṣadeede pariwo pe awọn ri ibọn lọwọ ẹ, ni wọn ba ki i mọlẹ, wọn si n pariwo pe gbọmọgbọmọ ni, niṣe lo fẹẹ jiiyan gbe.

Ariwo yii ni wọn lawọn eeyan gbọ, ti wọn fi bẹrẹ si i lu obinrin naa pẹlu okuta ati igi, leyin naa ni wọn dana sun un.

Kọmiṣanna ọlọpaa ni gbogbo iwadii tawọn ṣe, awọn o ri ibọn kankan, bẹẹ lawọn o ri ọmọ jojolo kankan nibi tobirin naa n gbe, baagi ti wọn si sọ pe ibọn wa ninu re ọhun ti dawati.

Odumosu ni awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lati Panti, Yaba, ti bẹrẹ iṣẹ ọfintoto lori iṣẹlẹ yii, wọn yoo si tu iṣu ọrọ naa desalẹ ikoko. O ni ijọba ko fara mọ kawọn araalu maa ṣedajọ afurasi ọdaran lọna aitọ bii eyi, ẹnikẹni tọwọ ofin ba si tẹ nidii aṣa bẹẹ yoo fẹnu fẹra bii abẹbẹ.

Leave a Reply