Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Titi dasiko yii lawọn eeyan ṣi n sọrọ nipa ọlọpaa kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Agnose Elijah, ẹni to ko awọn ọlọpaa mẹrin mi-in lẹyin lọ sileewe Girama Mary Immaculate, tọmọ rẹ n lọ l’ Ado-Ekiti, ti wọn si lu ọga ileewe ati tiṣa to lu ọmọ naa lalubami lọjọ Ẹti to kọja yii.
Gift Agnoise lọmọ ọlọpaa yii n jẹ, kilaasi akọkọ (J.S.S 1) lo wa nileeewe ọhun.
Irun buruku kan ni wọn ni Gift gẹ sori lọ sileewe lọjọ naa, tiṣa to si kọkọ ri i pe irun to gẹ yii ki i ṣe ti ọmọ gidi lo le e pada sile pe ko lọọ tun irun ọhun gẹ, iyẹn lẹyin to ti ja a lẹgba bii meloo kan.
Bi Gift ṣe dele to ṣalaye, to si tun fi apa ibi ti tiṣa ti na an han baba rẹ. Inu bi ọkunrin ọlọpaa naa, o si ni kọmọ oun niṣo nileewe, o loun yoo fi tiṣa rẹ naa jofin.
Ki wọn too maa lọ sileewe ni Baba Gift to jẹ inspẹkitọ ọlọpaa ti pe awọn ọmọọṣẹ rẹ mẹrin kan pe ki wọn kalọ sileewe naa, ki wọn jẹ kawọn da sẹria fawọn tiṣa ti wọn ko mọ bi ọmọ oun ṣe jẹ.
Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe ibọn lawọn ọlọpaa yii kọkọ da bolẹ bi wọn ṣe wọnu ọgba ileewe, ti wọn n yinbọn soke lakọlakọ, ti gbogbo awọn olukọ ati akẹkọọ si n sa kijokijo kiri. Eyi ni olori ileewe gbọ to fi jade sawọn ọlọpaa naa lati beere ohun to ṣẹlẹ. Ṣugbọn ibinu awọn agbofinro yii ni ọga ileewe ba pade, ni wọn ba mu ọga ileewe lu, wọn lu u titi to fi ṣubu lulẹ ni.
Bi wọn ti lu ọga ileewe tan ni wọn mu ọfiisi tiṣa to lu Gift pọn, lilu ko si to wiwọ foun naa gẹgẹ ba a ṣe gbọ. Wọn lu tiṣa naa ni aludojubolẹ to bẹẹ to jẹ awọn akẹkọọ atawọn tiṣa yooku n sa kijokijo kiri ni. Koda, gbogbo foonu awọn olukọ to jade si wọn ni wọn gba, ti wọn ko lọ. Bẹẹ ni wọn ko yee yinbọn soke, wọn ni niṣe ni iro ibọn n dun lakọlakọ.
Lẹyin ti wọn tẹ ara wọn lọrun tan ni wọn jade kuro ninu ọgba naa, niṣe ni wọn si n yinbọn soke bi wọn ṣe n lọ. Wọn mu Gift naa dani, oun naa ko wulẹ jokoo kẹkọọ mọ lọjọ naa, nitori ko tilẹ si tiṣa to le ṣiṣẹ kankan mọ.
Alaga ẹgbẹ awọn olukọ nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Ṣọla Adigun, ṣapejuwe iṣẹlẹ yii bii ohun ti ko bojumu rara. O ni awọn olukọ ti fa ọrọ naa le awọn ọlọpaa lọwọ lati ṣewadii ẹ, ki wọn si fi oju awọn agbofinro to jaye alabata naa han.
Adigun sọ pe bawọn ọlọpaa ko ba ṣiṣẹ naa bii iṣẹ, tabi ti wọn ba fẹẹ fẹjọ ṣegbe, o lawọn ajọ olukọ yoo fẹhonu han lọ sileeṣẹ wọn ni, o ni nitori eyi kọ ni igba akọkọ tawọn ọlọpaa yoo hu iru iwa bayii lawọn ileewe l’Ekiti.
Nigba to n fesi si eyi, Alukoro ọlọpaa l’Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe awọn ti fi oju awọn ọlọpaa naa han, awọn ko si fara mọ iwa irẹnijẹ tabi jagidijagan rara. O lawọn ti bẹrẹ iwadii lori ẹ, laipẹ ni ohun gbogbo to wa nidii iṣẹlẹ yii yoo foju han gbangba.