Ọlọpaa meji padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ lọna Ilọrin si Ogbomọṣọ

Stephen Ajagbe, Ilorin

 

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nijamba ọkọ gbẹmi ọlọpaa meji lagbegbe Ẹyẹnkọrin, lọna titi marosẹ Ilọrin si Ogbomọṣọ.

ALAROYE gbọ pe lasiko tawọn ọlọpaa naa n pada bọ lati Ogbomọṣọ, nibi ti wọn sin ọkọ agboworin kan lọ, ni ọkọ wọn lọọ rọ lu tirela kan to wa loju ọna naa.

Loju-ẹsẹ lawọn meji dagbere faye, ṣugbọn lara wọn fara pa.

Akọroyin wa gbọ pe wọn ti gbe oku awọn mejeeji lọ si mọṣuari nilewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH, nibẹ lawọn to fara pa naa ti n gba itọju.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe ọkan lara awọn taya ẹsẹ moto tawọn ọlọpaa naa gbe lọ si Ogbomọṣọ lo fọ lori ere, eyi lo si fa a ti ọkọ naa ṣe lọọ rọ lu ọkọ akẹru kan to wa loju titi.

 

 

Leave a Reply