Ọlọpaa mu eeyan mẹrindinlaaadọrin to lufin Korona nibi ayẹyẹ ọjọọbi l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 

 

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni awọn afurasi arufin mẹrindinlaaadọrin lo ko sakolo awọn lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, tori wọn ko pa ofin ati ilana arun Korona mọ, ayẹyẹ ọjọọbi ni wọn lawọn n ṣe, ibẹ ni wọn ti mu wọn.

Alukoro wọn, DSP Olumuyiwa Adejọbi, sọ pe DPO tẹsan ọlọpaa to wa lagbegbe Marọkọ loun atawọn ẹmẹwa ẹ lọọ fi pampẹ ofin gbe wọn nigba ti olobo ta wọn pe awọn eeyan kan ti dana ariya rẹpẹte si gbọngan to wa ni Lavender Court, Opopona Jakande, lagbegbe Oniru, to wa ni Victoria Island.

O ni yatọ si pe awọn alariyaa yii ko sọ fun ijọba, wọn ko si gba aṣẹ lati dana faaji bẹẹ, iye ero tawọn ba nibẹ ju iye tijọba la kalẹ fun ikorajọpọ lasiko arun Korona lọ, ọgọọrọ awọn ti wọn mu ni wọn ko tilẹ lo ibomu rara, awọn to si lo o ko wọ ọ daadaa bo ṣe yẹ.

Orukọ marun-un lara wọn ni Micheal Popoọla, Ọpẹyẹmi Adeyẹmọ, Ramọn Salami, Akeem Kareem ati Nurudeen Balogun, pẹlu awọn mọkanlelaaadọrin mi-in ti wọn fi pampẹ ofin gbe.

Wọn tun mu awọn ọkọ ayọkẹlẹ atawọn nnkan irinna bii aadoje (136) tawọn naa n rinde oru, lasiko ti ofin konilegbele aago mejila si mẹrin tijọba paṣẹ ṣi wa lẹnu iṣẹ.

Afẹmọju ọjọ naa ni wọn ti ko gbogbo wọn lọ sile-ẹjọ alaagbeka kan, wọn si ti dajọ wọn, wọn ti bu owo itanran to yẹ fun kaluku wọn. Bakan naa lawọn to ni mọto n sanwo itanran lati gba ọkọ wọn pada.

Alukoro ni ileeṣẹ ọlọpaa ko ni i foju ire wo ẹnikẹni to ba kuna lati pa aṣẹ ijọba lori arun Korona yii mọ.

 

 

 

Leave a Reply