Ọlọpaa n wa awọn ọmọ ọba meji, nitori ade iṣẹmabaye ti wọn ji lọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Pẹlu aṣẹ lati ọdọ ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede yii, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Warri, ẹkun Karun, ti fi orukọ awọn ọmọ ọba meji, Onyowoli ati Omatsuli  ti wọn jẹ ọmọ ọba to ana to gbesẹ ni Warri, sita pe awọn n wa wọn o.

Wọn ni ọwọ wọn ko mọ lori ade iṣembaye to sọnu laipẹ yii, bi ẹnikẹni ba ri wọn, ko tete fa wọn le ijọba lọwọ ni.

Ọjọ Abamẹta, Satide, to n bọ yii lo yẹ ki ọba tuntun ti wọn pe orukọ ẹ ni Tsola Emiko, gun ori itẹ baba rẹ gẹgẹ bii Olu Warri, nipinlẹ Delta. Afi bawọn kan ṣe ja wọ ibi ti ade iṣẹmbaye naa wa, ti wọn gbe e lọ pẹlu awọn nnkan pataki mi-in. Bẹẹ, ade ọhun lo yẹ kọba to fẹẹ jẹ lọjọ Satide de, irinwo ọdun ree (400 years) ti ade naa ti wa laafin ti nnkan kan ko mu un ko too di pe wọn waa ji i lọ yii.

Ohun ti a gbọ ni pe awọn ọmọọba meji yii lo wọ ibi ti ade ọhun wa, ti wọn gbe e sa lọ. Latigba ti wọn si ti ṣiṣẹ ọhun ni ẹnikẹni ko ti gburoo wọn mọ.

Ikede tawọn ọlọpaa fi sita ṣalaye nipa wọn, wọn ni ẹni ọgbọn ọdun ni Ọmọba Oyowoli, akẹkọọ ni, ọmọ Itṣekiri si ni. Awọn ọlọpaa ṣapejuwe pe o ga niwọn ẹsẹ bata marun-un ati diẹ, nigba ti aburo rẹ, Omatsuli, jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn. Wọn ni akẹkọọ loun naa nileewe, o si ga niwọn ẹsẹ bata marun-un ati diẹ naa ni.

Lọjọ Ẹti to kọja yii lawọn ọlọpaa ‘Zone 5’ ti kọkọ bẹrẹ ifọrọwanilẹnuwo to lagbara lori Olootu ijọba ilẹ Warri, Oloye Ayri Emami, ẹni ti wọn ti ni ko lọọ jokoo silẹ fungba diẹ na lori ade to sọnu yii. Iwadii ọhun ko si ti i pari, wọn ṣi wa lori ẹ digbi ni.

Oṣu kejila, ọdun 2020, to kọja yii, ni Olu Warri ana, Ogiame Ikenwoli, to jẹ baba awọn ọmọ ti wọn fẹsun ole kan yii papoda.

Boya iwuye to fẹẹ waye ni Satide yii, eyi ti wọn ti fẹẹ fi Ọmọba Tsola Emiko jẹ Olu Warri tuntun ko waa tẹ awọn ti wọn ni wọn ji ade lọ yii lọrun ni wọn ṣe palẹ ade mọ.

Ṣugbọn ko si ohun ti yoo di iwuye Olu Warri tuntun yii lọwọ ṣa gẹgẹ bawọn eleto ṣe wi, nitori wọn ni wọn ti pese ade mi-in to wuyi ju eyi ti wọn gbe lọ yii lọ

Leave a Reply