Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ idigunjale kan to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, niluu Ado-Ekiti, nibi tawọn agbebọn ti gba miliọnu lọna ogun lọwọ awọn oṣiṣẹ ijọba Ekiti kan ti wọn lọọ gbowo ni banki.
Gẹgẹ bi ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju ẹ ṣe sọ, awọn meji ni wọn lọọ gbowo ọhun ni banki lati ẹka kan ninu ile ijọba, agbegbe Bank Road, si ni ileefowopamọ naa wa. Bi wọn ṣe gba a tan ti wọn jade niṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ.
ALAROYE gbọ pe bi wọn ṣe rin diẹ sọna ile ijọba lawọn kan fi mọto dabuu ọkọ tiwọn, bi wọn si ṣe gba owo naa tan ni wọn lọri pada sọna GRA, eyi ti wọn le gba lọ siluu Ilawẹ-Ekiti.
Nitori bi wọn ṣe ni awọn agbebọn ọhun yinbọn soke lasiko iṣẹlẹ naa, ko sẹni to le duro, o si pẹ diẹ kawọn eeyan too mọ ohun to n ṣẹlẹ gan-an.
Iroyin iṣẹlẹ naa lo fa ibẹru nla lẹyin tawọn agbẹbọn ọhun lọ, awọn kan si n pariwo pe awọn ole ti ya bo banki l’Ado-Ekiti.