Ọlọpaa n wa awọn to gun Afeez pa ni Ẹrin-Ọṣun

Florence Babaṣọla

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun  ti bẹrẹ igbesẹ lori wiwa awọn ọmọkunrin mẹta ti wọn fẹsun kan pe won gun Afeez Kẹgbẹyale pa niluu Ẹrin Ọṣun.

Gẹgẹ bi ẹgbọn Afeez, Saheed Kẹgbẹyale ṣe sọ, ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ, ọjọ kin-in-ni oṣu kẹwaa. ọdun yii niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lasiko ti Afeez n pada bọ lati ibi to ti lọọ ra ounjẹ fun awọn adiyẹ rẹ.

Saheed ṣalaye pe ileewe gbogboniṣe to wa niluu Ọfa ni Afeez ti kẹkọọgboye ninu imọ ounjẹ (Food Science Technology), lẹyin to si pari isinru ilu nipinlẹ Bauchi, lo pinnu lati bẹrẹ iṣẹ agbẹ ati ọsin adiyẹ niluu Ẹrin Ọṣun.

O ni o gun ọkada fungba diẹ, nibẹ lo si ti tu owo jọ to fi ra oko nilu naa nibi to ti n ṣiṣẹ agbẹ.

Lalẹ ọjọ iṣẹlẹ naa, inu sunkẹrẹ-fakẹrẹ kan to waye loju-ọna ni itaporogan ti waye laarin Afeez to wa lori ọkada rẹ pẹlu awọn ọmọkunrin mẹta kan ti awọn naa gun ọkada mi-in.

Bi Afeez ṣe fẹẹ yọ kuro nibẹ la gbọ pe awọn ọmọkunrin ọhun fi ọkada wọn dena mọ ọn, wọn bẹrẹ si i na an, lẹyin naa ni wọn gun un lọbẹ laya, to si ku loju ẹsẹ.

Saheed ṣalaye siwaju pe ọmọ ọgbọn ọdun ni Afeez ati pe oun ni abigbẹyin iya rẹ. O ni ile igbokupamọsi ti ileewosan Aṣubiaro ni oku rẹ wa bayii.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa ati pe ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Falana lo lọ sọ fawọn ọlọpaa lalẹ ọjọ naa, ṣugbọn nigba ti wọn yoo fi debẹ, awọn ọmọkunrin naa ti sa lọ.

Ọpalọla ni awari ti obinrin n wa nnkan ọbẹ lawọn yoo fi ọrọ naa ṣe, awọn ko si ni i sinmi titi ti ọwọ yoo fi tẹ awọn ọkunrin mẹtẹẹta.

Leave a Reply